I. Sam 15:34-35
I. Sam 15:34-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu. Samuẹli kò sì padà wá mọ́ láti wo Saulu títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Samuẹli káàánú fún Saulu. Ó sì dun OLúWA pé ó fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli.
I. Sam 15:34-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli si lọ si Rama; Saulu si goke lọ si ile rẹ̀ ni Gibea ti Saulu. Samueli kò si tun pada wá mọ lati wo Saulu titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀: ṣugbọn Samueli kãnu fun Saulu: o si dùn Oluwa nitori on fi Saulu jẹ ọba lori Israeli.
I. Sam 15:34-35 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Samuẹli pada lọ sí Rama, Saulu ọba sì pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea ti Saulu. Samuẹli kò tún fi ojú kan Saulu mọ títí tí Samuẹli fi kú, ṣugbọn inú Samuẹli bàjẹ́ nítorí rẹ̀. Ọkàn OLUWA sì bàjẹ́ pé òun fi Saulu jọba Israẹli.