I. Sam 15:22-23
I. Sam 15:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli si wipe, Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ́? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ̀ si sàn jù ọra àgbo lọ. Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba.
I. Sam 15:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ. Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.”
I. Sam 15:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “OLúWA ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn OLúWA gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”