I. Pet 5:10-12
I. Pet 5:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ. Tirẹ̀ li ogo ati agbara titi lailai. Amin. Nipa Silfanu, arakunrin wa olõtọ gẹgẹbi mo ti ka a si, ni mo kọwe kukuru si nyin, ti mo ngbà nyin niyanju, ti mo si njẹri pe, eyi ni otitọ ore-ọfẹ Ọlọrun: ẹ duro ṣinṣin ninu rẹ̀.
I. Pet 5:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀. Òun ni agbára wà fún laelae. Amin. Silifanu ni ó bá mi kọ ìwé kúkúrú yìí si yín. Mo ka Silifanu yìí sí arakunrin tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹ dúró lórí ohun tí mo kọ.
I. Pet 5:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín. Nítorí Sila, arákùnrin wa olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkúrú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.