I. Pet 4:15-16
I. Pet 4:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ninu nyin ki o jìya bi apania, tabi bi olè, tabi bi oluṣe-buburu, tabi bi ẹniti ntojubọ ọ̀ran ẹlomiran. Ṣugbọn bi o ba jìya bi Kristiani, ki oju ki o máṣe tì i; ṣugbọn ki o kuku yìn Ọlọrun logo ni orukọ yi.

I. Pet 4:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Tí ẹ bá níláti jìyà, kí ó má jẹ́ gẹ́gẹ́ bí apànìyàn, tabi olè, tabi eniyan burúkú, tabi ẹni tí ń tojú bọ nǹkan-oní-nǹkan. Ṣugbọn bí ẹ bá jìyà gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ẹ má jẹ́ kí ó tì yín lójú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa yin Ọlọrun lógo fún orúkọ tí ẹ̀ ń jẹ́.
I. Pet 4:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí.