I. Pet 4:12-14
I. Pet 4:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olufẹ, ẹ máṣe ka idanwò iná ti mbẹ larin nyin eyiti o de si nyin lati dan nyin wò bi ẹnipe ohun àjeji li o de bá nyin: Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn. Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo.
I. Pet 4:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹ má jẹ́ kí ó jọ yín lójú bí wọ́n bá wa iná jó yín láti dán yín wò, bí ẹni pé ohun tí ojú kò rí rí ni ó dé. Èyí sọ yín di alábàápín ninu ìjìyà Kristi. Ẹ máa yọ̀. Nígbà tí ó bá pada dé ninu ògo rẹ̀, ayọ̀ ńlá ni ẹ óo yọ̀. Bí wọn bá ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí orúkọ Kristi, ẹ ṣe oríire, nítorí Ẹ̀mí tí ó lógo nnì, Ẹ̀mí Ọlọrun, ti bà lé yín lórí.
I. Pet 4:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín.