I. Pet 1:9-16
I. Pet 1:9-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin si ngbà opin igbagbọ́ nyin, ani igbala ọkàn nyin; Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ̀ fun nyin: Nwọn nwadi igba wo tabi irú sã wo ni Ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọ́ka si, nigbati o jẹri ìya Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹlé e. Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò. Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi: Bi awọn eleti ọmọ, li aifi ara nyin dáṣà bi ifẹkufẹ atijọ ninu aimọ̀ nyin: Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo: Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹ jẹ mimọ́; nitoriti mo jẹ mimọ́.
I. Pet 1:9-16 Yoruba Bible (YCE)
nítorí pé ẹ jèrè igbagbọ yín nípa ìgbàlà ọkàn yín. Àwọn wolii tí wọ́n ṣe ìkéde oore-ọ̀fẹ́ tún fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ìgbàlà yìí. Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀. Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi. Nítorí náà, ẹ ṣe ọkàn yìn gírí. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́. Ẹ máa retí oore-ọ̀fẹ́ tí yóo jẹ́ tiyín nígbà tí Jesu Kristi bá tún dé. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ń gbọ́ràn, ẹ má gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Ọlọrun ní, “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí èmi náà jẹ́ mímọ́.”
I. Pet 1:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín. Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò. Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”