I. Pet 1:8-12
I. Pet 1:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti ẹnyin fẹ lairi, ẹniti ẹnyin gbagbọ, bi o tilẹ ṣepe ẹ kò ri i nisisiyi, ẹnyin si nyọ ayọ̀ ti a kò le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo: Ẹnyin si ngbà opin igbagbọ́ nyin, ani igbala ọkàn nyin; Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ̀ fun nyin: Nwọn nwadi igba wo tabi irú sã wo ni Ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọ́ka si, nigbati o jẹri ìya Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹlé e. Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.
I. Pet 1:8-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i, sibẹ ẹ fẹ́ràn rẹ̀. Ẹ kò rí i sójú nisinsinyii, sibẹ ẹ gbà á gbọ́, ẹ sì ń yọ ayọ̀ tí ẹnu kò lè sọ, ayọ̀ tí ó lógo, nítorí pé ẹ jèrè igbagbọ yín nípa ìgbàlà ọkàn yín. Àwọn wolii tí wọ́n ṣe ìkéde oore-ọ̀fẹ́ tún fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ìgbàlà yìí. Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀. Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.
I. Pet 1:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín. Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.