I. Pet 1:3-6
I. Pet 1:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú, Sinu ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá, ti a ti fi pamọ́ li ọrun dè nyin, Ẹnyin ti a npamọ́ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ́ si igbala, ti a mura lati fihàn ni igba ikẹhin. Ninu eyiti ẹnyin nyọ̀ pipọ, bi o tilẹ ṣe pe nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọ̀pọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ
I. Pet 1:3-6 Yoruba Bible (YCE)
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú. Ó fún wa ni ogún ainipẹkun, ogún tí kò lè díbàjẹ́, tí kò lè ṣá, tí a ti fi pamọ́ fun yín ní ọ̀run. Ẹ̀yin ni a ti dáàbò bò nípa agbára Ọlọrun nípa igbagbọ sí ìgbàlà tí a ti ṣe ètò láti fihàn ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹ máa yọ̀ nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún àkókò díẹ̀, ẹ níláti ní ìdààmú nípa oríṣìíríṣìí ìdánwò.
I. Pet 1:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́