I. Pet 1:1-2
I. Pet 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia, ati Bitinia, Gẹgẹ bi ìmọtẹlẹ Ọlọrun Baba, nipa isọdimimọ́ Ẹmí, si igbọran ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ Jesu Kristi: Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bi si i fun nyin.
I. Pet 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia. Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.
I. Pet 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Peteru, aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia, àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi