I. A. Ọba 9:10-28

I. A. Ọba 9:10-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba. Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili. Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u. On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi. Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba. Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri. Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ. Solomoni si kọ́ Geseri, ati Bethoroni-isalẹ. Ati Baalati, ati Tadmori ni aginju, ni ilẹ na. Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀. Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli. Awọn ọmọ wọn ti o kù lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò le parun tũtu, awọn ni Solomoni bù iṣẹ-iru fun titi di oni yi. Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli, Solomoni kò fi ṣe ẹrú, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ologun ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn balogun rẹ̀, ati awọn olori kẹkẹ́ rẹ̀ ati ti awọn ẹlẹsin rẹ̀. Awọn wọnyi ni awọn olori olutọju ti mbẹ lori iṣẹ Solomoni, ãdọta-dilẹgbẹta, ti nṣe akoso lori awọn enia ti nṣe iṣẹ na. Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo. Ati nigba mẹta li ọdun ni Solomoni iru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ẹbọ-ọpẹ lori pẹpẹ ti o tẹ́ fun Oluwa, o si sun turari lori eyi ti mbẹ niwaju Oluwa. Bẹ̃li o pari ile na. Solomoni ọba si sẹ ọ̀wọ-ọkọ̀ ni Esioni-Geberi, ti mbẹ li ẹba Eloti, leti Okun-pupa ni ilẹ Edomu. Hiramu si rán awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn atukọ ti o ni ìmọ okun, pẹlu awọn iranṣẹ Solomoni ninu ọ̀wọ-ọkọ̀ na. Nwọn si de Ofiri, nwọn si mu wura lati ibẹ wá, irinwo talenti o le ogun, nwọn si mu u fun Solomoni ọba wá.

I. A. Ọba 9:10-28 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili. Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá. Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí. Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba. Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri. (Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba. Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni, ati ìlú Baalati, ati Tamari tí ó wà ní aṣálẹ̀ Juda, ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli– arọmọdọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè parun, ni Solomoni kó lẹ́rú pẹlu ipá, wọ́n sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní yìí. Ṣugbọn Solomoni kò fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹrú. Àwọn ni ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun, ati olórí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀; àwọn ni balogun rẹ̀, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀; àwọn ni ọ̀gá àwọn tí ń darí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Ẹgbẹta ó dín aadọta (550) ni àwọn lọ́gàálọ́gàá tí Solomoni fi ṣe alákòóso àwọn tí ó ń kó ṣiṣẹ́ tipátipá, níbi oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ilé kíkọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó yá, ọmọ ọba Farao, iyawo Solomoni kó kúrò ní ìlú Dafidi, ó lọ sí ilé tí Solomoni kọ́ fún un. Lẹ́yìn náà ni Solomoni kọ́ ìlú Milo. Ẹẹmẹta lọ́dún ni Solomoni máa ń rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia lórí pẹpẹ tí ó kọ́ fún OLUWA, a sì máa sun turari níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí kíkọ́ ilé náà. Solomoni kan ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi ní Esiongeberi lẹ́bàá Eloti, ní etí Òkun Pupa ní ilẹ̀ Edomu. Hiramu ọba fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi, lé àwọn ọkọ̀ náà, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ Solomoni sí i. Wọ́n tu ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Ofiri, wọ́n sì kó wúrà tí ó tó okoolenirinwo (420) ìwọ̀n talẹnti bọ̀ wá fún Solomoni ọba.

I. A. Ọba 9:10-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé OLúWA àti ààfin ọba. Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn. Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí. Hiramu sì ti fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba. Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé OLúWA àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, Àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso. Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli, ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí. Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà. Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo. Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún OLúWA, ó sì sun tùràrí níwájú OLúWA pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà. Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa. Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Wọ́n sì dé ofiri, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.