I. A. Ọba 8:1-21

I. A. Ọba 8:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Solomoni papejọ awọn agba Israeli, ati gbogbo awọn olori awọn ẹ̀ya, awọn olori awọn baba awọn ọmọ Israeli, si ọdọ Solomoni ọba ni Jerusalemu, ki nwọn ki o lè gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá lati ilu Dafidi, ti iṣe Sioni. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pe ara wọn jọ si ọdọ Solomoni ọba ni ajọ ọdun ni oṣu Etanimu, ti iṣe oṣu keje. Gbogbo awọn agbàgba Israeli si wá, awọn alufa si gbe apoti-ẹri. Nwọn si gbe apoti-ẹ̀ri Oluwa wá soke, ati agọ ajọ enia, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ ani nkan wọnni ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi gbe goke wá. Ati Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀ niwaju apoti-ẹri, nwọn nfi agutan ati malu ti a kò le mọ̀ iye, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ rubọ. Awọn alufa si gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀ sinu ibi-idahùn ile na, ni ibi mimọ́-julọ labẹ iyẹ awọn kerubu. Nitori awọn kerubu nà iyẹ wọn mejeji si ibi apoti-ẹri, awọn kerubu na si bò apọti-ẹri ati awọn ọpá rẹ̀ lati oke wá. Nwọn si fa awọn ọpá na jade tobẹ̃ ti a nfi ri ori awọn ọpá na lati ibi mimọ́ niwaju ibi-idahùn, a kò si ri wọn lode: nibẹ ni awọn si wà titi di oni yi. Kò si nkankan ninu apoti-ẹri bikoṣe tabili okuta meji, ti Mose ti fi si ibẹ ni Horebu nigbati Oluwa ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti ilẹ Egipti jade. O si ṣe, nigbati awọn alufa jade lati ibi mimọ́ wá, awọsanma si kún ile Oluwa. Awọn alufa kò si le duro ṣiṣẹ nitori awọsanma na: nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa. Nigbana ni Solomoni sọ pe: Oluwa ti wi pe, on o mã gbe inu okùnkun biribiri. Nitõtọ emi ti kọ́ ile kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀, ibukojo kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀ titi lai. Ọba si yi oju rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ enia Israeli: gbogbo ijọ enia Israeli si dide duro; O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe, Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi. O si wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. Oluwa si wi fun Dafidi baba mi pe, Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ. Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. Emi si ti ṣe àye kan nibẹ̀ fun apoti-ẹri, ninu eyiti majẹmu Oluwa gbe wà, ti o ti ba awọn baba wa dá, nigbati o mu wọn jade lati ilẹ Egipti wá.

I. A. Ọba 8:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà Israẹli: àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ati gbogbo àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ó pè wọ́n jọ sí Jerusalẹmu láti gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu ilé OLÚWA. Gbogbo wọ́n bá péjọ siwaju rẹ̀ ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù Etanimu, tíí ṣe oṣù keje ọdún. Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa gbé Àpótí OLUWA wá, ati Àgọ́ OLUWA, ati àwọn ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Solomoni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli péjọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, wọ́n sì fi ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù tí ẹnikẹ́ni kò lè kà rúbọ. Lẹ́yìn náà, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu ibi mímọ́ ti inú, ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kerubu. Nítorí àwọn kerubu yìí na ìyẹ́ wọn bo ibi tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí náà sí, wọ́n sì dàbí ìbòrí fún Àpótí Ẹ̀rí ati àwọn ọ̀pá rẹ̀. Àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbé Àpótí Ẹ̀rí náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ẹni tí ó bá dúró ninu Ibi-Mímọ́ fi lè rí orí wọn níwájú Ibi-Mímọ́ ti inú. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí wọn láti ìta. Àwọn ọ̀pá náà wà níbẹ̀ títí di òní yìí. Kò sí ohunkohun ninu Àpótí Ẹ̀rí náà, àfi tabili òkúta meji tí Mose kó sinu rẹ̀ ní òkè Sinai, níbi tí OLUWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu, nígbà tí wọn ń ti Ijipti bọ̀. Bí àwọn alufaa ti jáde láti inú Ibi-Mímọ́ náà, ìkùukùu kún inú rẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA. Solomoni bá gbadura, ó ní, “OLUWA, ìwọ ni o fi oòrùn sí ojú ọ̀run, ṣugbọn sibẹsibẹ o yàn láti gbé inú ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Nisinsinyii mo ti kọ́ ilé kan tí ó lọ́lá fún ọ, níbi tí o óo máa gbé títí lae.” Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn. Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní, ‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ” Solomoni tún fi kún un pé, “Ó jẹ́ èrò ọkàn baba mi láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún un pé nítòótọ́, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti kọ́ ilé fún mi, ó sì dára bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.”

I. A. Ọba 8:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Israẹli jọ papọ̀, níwájú Solomoni ọba ní Jerusalẹmu, láti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA wá láti ìlú Dafidi, tí ń ṣe Sioni. Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Solomoni ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Etanimu tí í ṣe oṣù keje. Nígbà tí gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi sì gbé wọn gòkè wá, Àti Solomoni ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rú ẹbọ. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLúWA wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e. Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti ibi mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde ibi mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. Kò sí ohun kankan nínú àpótí ẹ̀rí bí kò ṣe wàláà òkúta méjì tí Mose ti fi sí ibẹ̀ ní Horebu, níbi tí OLúWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, àwọsánmọ̀ sì kún ilé OLúWA. Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọsánmọ̀ náà, nítorí ògo OLúWA kún ilé náà. Nígbà náà ni Solomoni sì wí pé, “OLúWA ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri; Nítòótọ́, èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.” Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn. Nígbà náà ni ó wí pé: “Ìbùkún ni fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dafidi láti ṣàkóso àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ “Dafidi baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Ṣùgbọ́n OLúWA sì wí fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ. Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’ “OLúWA sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dafidi baba mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli báyìí, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú OLúWA tí ó ti bá àwọn baba wa dá, nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”