I. A. Ọba 7:1-12

I. A. Ọba 7:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN Solomoni fi ọdun mẹtala kọ́ ile on tikararẹ̀, o si pari gbogbo iṣẹ ile rẹ̀. O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na. A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́. Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn. O si ṣe iloro itẹ nibiti yio ma ṣe idajọ, ani iloro idajọ: a si fi igi kedari tẹ ẹ lati iha kan de keji. Ile rẹ̀ nibiti o ngbe, ni agbala lẹhin ile titi de ọ̀dẹdẹ, si jẹ iṣẹ kanna. Solomoni si kọ́ ile fun ọmọbinrin Farao, ti o ni li aya, bi iloro yi. Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla. Ipilẹ na jẹ okuta iyebiye, ani okuta nlanla, okuta igbọnwọ mẹwa, ati okuta igbọnwọ mẹjọ. Ati okuta iyebiye wà loke nipa iwọ̀n okuta ti a gbẹ́, ati igi kedari. Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na.

I. A. Ọba 7:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Ọdún mẹtala ni Solomoni fi parí kíkọ́ ilé ti ara rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé. Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí. Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta. Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo. Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà. Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà. Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀. Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé.

I. A. Ọba 7:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Solomoni sì lo ọdún mẹ́tàlá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀. Ó kọ́ ilé igbó Lebanoni pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kedari, àti ìdábùú igi kedari lórí òpó náà. A sì fi igi kedari tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ́n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọ̀wọ́. Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn. Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn. Ó sì fi ọ̀wọ́n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn. Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kedari bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Solomoni sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Farao tí ó ní ní aya. Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde. Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńláńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ àti igi kedari. Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kedari, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé OLúWA pẹ̀lú ìloro rẹ̀.