I. A. Ọba 4:1-34

I. A. Ọba 4:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

SOLOMONI ọba si jẹ ọba lori gbogbo Israeli. Awọn wọnyi ni awọn ijoye ti o ni; Asariah, ọmọ Sadoku alufa, Elihorefu ati Ahiah, awọn ọmọ Ṣiṣa li akọwe, Jehoṣafati ọmọ Ahiludi li akọwe ilu. Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa: Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba: Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú. Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese. Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu. Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani: Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi: Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. Baana ọmọ Ahiludi, tirẹ̀ ni Taanaki iṣe, ati Megiddo, ati gbogbo Betṣeani ti mbẹ niha Sartana nisalẹ Jesreeli, lati Betṣeani de Abelmehola, ani titi de ibi ti mbẹ ni ikọja Jokneamu; Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ. Ahinadabu, ọmọ Iddo, li o ni Mahanaimu. Ahimaasi wà ni Naftali; on pẹlu li o ni Basmati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. Baana, ọmọ Huṣai wà ni Aṣeri ati ni Aloti. Jehoṣafati, ọmọ Paruha, ni Issakari: Ṣimei, ọmọ Ela, ni Benjamini. Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na. Juda ati Israeli pọ̀ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọ̀pọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya. Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀. Onjẹ Solomoni fun ijọ kan jasi ọgbọ̀n iyẹ̀fun kikunna ati ọgọta oṣuwọn iyẹ̀fun iru miran. Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra. Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri. Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni. Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin. Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù. Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀. Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun. Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti. On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka. O si pa ẹgbẹdọgbọn owe: orin rẹ̀ si jẹ ẹgbẹrun o le marun. O si sọ̀rọ ti igi, lati kedari ti mbẹ ni Lebanoni, ani titi de hissopu ti nhu lara ogiri: o si sọ̀ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹiyẹ, ati ohun ti nrako, ati ti ẹja. Ẹni pupọ si wá lati gbogbo orilẹ-ède lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni; ani lati ọdọ gbogbo awọn ọba aiye, ti o gburo ọgbọ́n rẹ̀.

I. A. Ọba 4:1-34 Yoruba Bible (YCE)

Solomoni jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli, Orúkọ àwọn olórí ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Asaraya, ọmọ Sadoku ni alufaa. Elihorefi ati Ahija, meji ninu àwọn ọmọ Ṣiṣa ni akọ̀wé ní ààfin ọba. Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ni balogun. Sadoku ati Abiatari jẹ́ alufaa, Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba. Ahiṣari ni olùdarí gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ààfin. Adoniramu ọmọ Abida ni olórí àwọn tí ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá. Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan. Orúkọ àwọn alákòóso mejeejila ati agbègbè tí olukuluku wọn ń mójú tó nìwọ̀nyí: Benhuri ní ń ṣe àkóso agbègbè olókè Efuraimu; Bẹndekeri ni alákòóso fún ìlú Makasi, ati Ṣaalibimu, ìlú Beti Ṣemeṣi, Eloni, ati Beti Hanani. Benhesedi ní Aruboti ni alákòóso fún ìlú Aruboti, ati Soko, ati gbogbo agbègbè Heferi. Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori. Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu. Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.) Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu. Ahimaasi, (ọkọ Basemati, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Solomoni), ni alákòóso Nafutali. Baana, ọmọ Huṣai, ni alákòóso agbègbè Aṣeri, ati Bealoti. Jehoṣafati, ọmọ Parua, ni alákòóso agbègbè Isakari. Ṣimei, ọmọ Ela, ni alákòóso agbègbè Bẹnjamini. Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda. Àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bíi yanrìn inú òkun, wọ́n ń rí jẹ, wọ́n ń rí mu, wọ́n sì láyọ̀. Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Àwọn nǹkan tí Solomoni ń lò fún ìtọ́jú oúnjẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: Ọgbọ̀n òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, ati ọgọta òṣùnwọ̀n ọkà tí wọ́n lọ̀; àbọ́pa mààlúù mẹ́wàá, ogún mààlúù tí wọn ń dà ninu pápá, ati ọgọrun-un aguntan; láìka àgbọ̀nrín, egbin, ìgalà, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ àbọ́pa. Solomoni jọba lórí gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate, láti ìlú Tifisa, títí dé ìlú Gasa, ati lórí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate; alaafia sì wà láàrin òun ati àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Ní gbogbo àkókò Solomoni, gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli wà ní alaafia láti ìlú Dani títí dé Beeriṣeba. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ọgbà àjàrà ati àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀. Ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni ilé tí Solomoni kọ́ fún àwọn ẹṣin tí ń fa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì ní ẹgbaafa (12,000) eniyan tí ń gun ẹṣin. Alákòóso kọ̀ọ̀kan níí máa tọ́jú nǹkan jíjẹ tí Solomoni ọba ń lò fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn tí ń jẹun ní ààfin rẹ̀; alákòóso kọ̀ọ̀kan sì ní oṣù tí ó gbọdọ̀ pèsè nǹkan jíjẹ, láìjẹ́ kí ohunkohun dín ninu ohun tí ọba nílò. Wọn a sì máa mú ọkà baali ati koríko wá fún àwọn ẹṣin tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹṣin tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Olukuluku a máa mú ohun tí wọ́n bù fún un wá sí ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀. Ọgbọ́n ati òye tí Ọlọrun fún Solomoni kọjá sísọ, ìmọ̀ rẹ̀ sì kọjá ìwọ̀n. Solomoni gbọ́n ju àwọn amòye ìhà ìlà oòrùn ati ti Ijipti lọ. Òun ni ó gbọ́n jùlọ ní gbogbo ayé. Ó gbọ́n ju Etani ará Ẹsira lọ, ati Hemani, ati Kakoli, ati Dada, àwọn ọmọ Maholi. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ni òwe tí òun nìkan pa, orin tí òun nìkan kọ sì jẹ́ marunlelẹgbẹrun. Ó sọ nípa igi, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí igi kedari ti ilẹ̀ Lẹbanoni, títí kan Hisopu tí ó ń hù lára ògiri. Ó sọ nípa àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, àwọn ohun tí ń fi àyà fà ati àwọn ẹja. Àwọn eniyan sì ń wá láti oniruuru orílẹ̀ èdè, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, tí wọ́n ti gbúròó nípa ọgbọ́n rẹ̀, wọn á wá tẹ́tí sí ọgbọ́n rẹ̀.

I. A. Ọba 4:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Solomoni ọba sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà: Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú; Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà; Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sobudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn; Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú. Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún. Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu. Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani; Bene-Hesedi, ní Aruboti; tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe; Bene-Abinadabu, ní Napoti Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya. Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu; Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi; tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta (60) ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin. Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu Ahimasi ní Naftali; ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya; Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti; Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari; Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini; Geberi ọmọ Uri ní Gileadi; orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà. Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀. Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n (30) ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun, Màlúù mẹ́wàá (10) tí ó sanra, àti ogún (20) màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra. Nítorí òun ni ó ṣàkóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Eufurate, láti Tifisa títí dé Gasa, lórí gbogbo àwọn ọba ní ìhà ìhín odò, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó yí i káàkiri. Nígbà ayé Solomoni, Juda àti Israẹli, láti Dani títí dé Beerṣeba, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀. Solomoni sì ní ẹgbàajì (40,000) ilé ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà (12,000) ẹlẹ́ṣin. Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Solomoni ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá sí ibi tábìlì ọba, wọ́n sì rí i pé ohun kankan kò ṣẹ́kù. Wọ́n tún máa ń mú ọkà barle àti koríko fún ẹṣin àti fún ẹṣin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀. Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun. Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ. Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká. Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (1,005). Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja. Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.