I. A. Ọba 3:9-14
I. A. Ọba 3:9-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina, fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ̀ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi? Ọ̀rọ na si dara loju Oluwa, nitoriti Solomoni bère nkan yi. Ọlọrun si wi fun u pe, Nitoriti iwọ bère nkan yi, ti iwọ kò si bère ẹmi gigun fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ọlá fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ẹmi awọn ọta rẹ; ṣugbọn iwọ bère oye fun ara rẹ lati mọ̀ ẹjọ-idá; Wò o, emi ti ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, wò o, emi fun ọ ni ọkàn ọgbọ́n ati imoye; tobẹ̃ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣãju rẹ, bẹ̃ni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ. Ati eyiti iwọ kò bere, emi o fun ọ pẹlu ati ọrọ̀ ati ọlá: tobẹ̃ ti kì yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ. Bi iwọ o ba si rìn ni ọ̀na mi lati pa aṣẹ ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ ti rìn, emi o si sún ọjọ rẹ siwaju.
I. A. Ọba 3:9-14 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?” Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè. Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.”
I. A. Ọba 3:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?” Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”