I. A. Ọba 3:1-2
I. A. Ọba 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
SOLOMONI si ba Farao ọba Egipti da ana, o si gbe ọmọbinrin Farao ni iyawo, o si mu u wá si ilu Dafidi, titi o fi pari iṣẹ ile rẹ̀, ati ile Oluwa, ati odi Jerusalemu yika. Kiki pe, awọn enia nrubọ ni ibi giga, nitori a kò ti ikọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, titi di ọjọ wọnnì.
I. A. Ọba 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́. Oríṣìíríṣìí pẹpẹ ìrúbọ ni àwọn eniyan tẹ́ káàkiri, tí wọ́n sì ń rúbọ lórí wọn, nítorí wọn kò tí ì kọ́ ilé OLUWA nígbà náà.
I. A. Ọba 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili OLúWA, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tí ì kọ́ ilé fún orúkọ OLúWA títí di ìgbà náà