I. A. Ọba 22:1-53

I. A. Ọba 22:1-53 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌDUN mẹta si rekọja laisi ogun lãrin Siria ati lãrin Israeli. O si ṣe li ọdun kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda sọkalẹ tọ ọba Israeli wá. Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria? O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi. Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀? Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃. Ọba Israeli si pè iwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah, ọmọ Imla, ki o yara wá. Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn. Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn. Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe: Goke lọ si Ramoti-Gileadi, ki o si ṣe rere: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere. Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti wà, ohun ti Oluwa ba sọ fun mi li emi o sọ. Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bu pe, ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikoṣe otitọ li orukọ Oluwa? On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò sọ fun ọ, pe on kì o fọ̀ ire si mi, bikoṣe ibi? On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀. Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ki o le goke lọ, ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ẹnikan si wi bayi, ẹlomiran si sọ miran. Ẹmi kan si jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi-eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ. Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana sunmọ ọ, o si lu Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ? Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o lọ lati inu iyẹwu de iyẹwu lati fi ara rẹ pamọ. Ọba Israeli si wipe, Mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba: Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi: Ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia. Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ipa mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo! Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà. Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan. O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe. O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀. Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ. Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na. A si kede la ibudo já li akokò iwọ̀ õrun wipe, Olukuluku si ilu rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀. Bẹ̃ni ọba kú, a si gbe e wá si Samaria; nwọn si sin ọba ni Samaria. Ẹnikan si wẹ kẹkẹ́ na ni adagun Samaria, awọn ajá si la ẹ̀jẹ rẹ̀; awọn àgbere si wẹ ara wọn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ, Ati iyokù iṣe Ahabu, ati gbogbo eyi ti o ṣe, ati ile ehin-erin ti o kọ́, ati gbogbo ilu ti o tẹ̀do, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Ahabu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Ahasiah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ Asa, si bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda li ọdun kẹrin Ahabu, ọba Israeli. Jehoṣafati si to ẹni ọdun marundilogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mẹ̃dọgbọn ni Jerusalẹmu. Orukọ iya rẹ̀ ni Asuba ọmọbinrin Ṣilhi. O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni. Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na. Nigbana kò si ọba ni Edomu: adelé kan li ọba. Jehoṣafati kàn ọkọ̀ Tarṣiṣi lati lọ si Ofiri fun wura; ṣugbọn nwọn kò lọ: nitori awọn ọkọ̀ na fọ́ ni Esion-Geberi. Nigbana ni Ahasiah, ọmọ Ahabu, wi fun Jehoṣafati pe, Jẹ ki awọn iranṣẹ mi ba awọn iranṣẹ rẹ lọ ninu ọkọ̀. Ṣugbọn Jehoṣafati kọ̀. Jehoṣafati si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi, baba rẹ̀: Jehoramu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. Ahasiah, ọmọ Ahabu, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kẹtadilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun meji lori Israeli. O si ṣe ibi niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati li ọ̀na iya rẹ̀, ati li ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ: Nitoriti o sin Baali, o si mbọ ọ, o si mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.

I. A. Ọba 22:1-53 Yoruba Bible (YCE)

Fún ọdún mẹta lẹ́yìn èyí, kò sí ogun rárá láàrin ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Siria. Nígbà tí ó di ọdún kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda, lọ bẹ Ahabu, ọba Israẹli wò. Ahabu bi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa ni a ni ìlú Ramoti Gileadi? A kò sì ṣe ohunkohun láti gbà á pada lọ́wọ́ ọba Siria.” Ó bi Jehoṣafati pé, “Ṣé o óo bá mi lọ, kí á jọ lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati bá dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ti yá ọ, ó yá mi. Tìrẹ ni àwọn eniyan mi, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin mi pẹlu.” Jehoṣafati fi ṣugbọn kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ OLUWA ná.” Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ? Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.” Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè pé, “Ṣé kò tún sí wolii OLUWA mìíràn mọ́, tí a lè wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀?” Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.” Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá. Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.” Nǹkan kan náà ni gbogbo àwọn wolii yòókù ń wí, gbogbo wọn ní kí Ahabu lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, wọ́n ní OLUWA yóo fún un ní ìṣẹ́gun. Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.” Ṣugbọn Mikaaya dáhùn pé, “OLUWA alààyè, ń gbọ́! Ohun tí OLUWA bá wí fún mi ni n óo sọ.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọba, ọba bi í pé, “Mikaaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi ni, àbí kí á má lọ?” Mikaaya dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.” Ṣugbọn Ahabu tún bi í pé, “Ìgbà mélòó ni n óo sọ fún ọ pé, nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ fún mi ní orúkọ OLUWA, kí o máa sọ òtítọ́ fún mi?” Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ” Ahabu bá wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi burúkú?” Mikaaya dáhùn pé, “Ó dára, fetí sílẹ̀, kí o gbọ́ ohun tí OLUWA wí, mo rí i tí OLUWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ati tòsì, OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu jẹ, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi kí wọ́n sì pa á níbẹ̀?’ Bí angẹli kan ti ń sọ ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni òmíràn sì ń sọ nǹkan mìíràn. Ẹ̀mí kan bá jáde siwaju OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tàn án jẹ.’ OLUWA bá bi í pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o óo dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo mú kí gbogbo àwọn wolii Ahabu purọ́ fún un.’ OLUWA bá dáhùn pé, ‘Lọ tàn án jẹ, o óo ṣe àṣeyọrí.’ “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, OLUWA ni ó jẹ́ kí àwọn wolii wọnyi máa purọ́ fún ọ, nítorí pé ó ti pinnu láti jẹ́ kí ibi bá ọ.” Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.” Mikaaya bá dá a lóhùn pé, “O óo rí i nígbà tí ó bá di ọjọ́ náà, tí o bá sá wọ yàrá inú patapata lọ, láti fi ara pamọ́.” Ọba Israẹli bá dáhùn pé, “Ẹ mú Mikaaya pada lọ fún Amoni, gomina ìlú yìí, ati Joaṣi ọmọ ọba. Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.” Mikaaya bá dáhùn pé, “Bí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ló gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó ní, “Gbogbo eniyan, ṣé ẹ gbọ́ ohun tí mo wí?” Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́. Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, wọ́n kéde fún gbogbo àwọn ọmọ ogun pé, “Kí olukuluku pada sí agbègbè rẹ̀! Kí kaluku kọrí sí ìlú rẹ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ. Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Lẹ́yìn tí òun kú ni Ahasaya ọmọ rẹ̀ gun orí oyè. Ní ọdún kẹrin tí Ahabu, ọba Israẹli, gun orí oyè, ni Jehoṣafati, ọmọ Asa, gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọmọ ọdún marundinlogoji ni Jehoṣafati nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹẹdọgbọn. Asuba ọmọ Ṣilihi ni ìyá rẹ̀. Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀. Jehoṣafati bá ọba Israẹli ṣọ̀rẹ́, alaafia sì wà láàrin wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe, gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ati gbogbo ogun tí ó jà, wà ninu àkọsílẹ̀ Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí ó kù ní ilé àwọn oriṣa láti àkókò Asa, baba rẹ̀, ni ó parun ní ilẹ̀ náà. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà. Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi. Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà. Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀. Ní ọdún kẹtadinlogun tí Jehoṣafati, ọba Juda, gun orí oyè ni Ahasaya, ọmọ Ahabu, gun orí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba ní Samaria fún ọdún meji. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ó bọ oriṣa Baali, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú ní gbogbo ọ̀nà bí baba rẹ̀ ti ṣe.

I. A. Ọba 22:1-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Fún ọdún mẹ́ta kò sì sí ogun láàrín Aramu àti Israẹli. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, Jehoṣafati ọba Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Israẹli. Ọba Israẹli sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gileadi, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Aramu?” Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jehoṣafati pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti Gileadi jà?” Jehoṣafati sì dá ọba Israẹli lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.” Ṣùgbọ́n Jehoṣafati sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ OLúWA.” Nígbà náà ni ọba Israẹli kó àwọn wòlíì jọ, bí irínwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti Gileadi lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ǹjẹ́ wòlíì OLúWA kan kò sí níhìn-ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ OLúWA, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Mikaiah ọmọ Imla ni.” Jehoṣafati sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli sì pe ìránṣẹ́ kan, ó sì wí pé, “Lọ yára mú Mikaiah, ọmọ Imla wá.” Ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnu ibodè Samaria, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. Sedekiah ọmọ Kenaana sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLúWA wí: ‘Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Aramu títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ ” Gbogbo àwọn wòlíì tókù sì ń sọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà wí pé, “Kọlu Ramoti Gileadi, kí o sì ṣẹ́gun.” Wọ́n sì wí pé, “nítorí tí OLúWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Mikaiah wí fún un pé, “Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere.” Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pé, “Bí OLúWA ti wà, ohun tí OLúWA bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un.” Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaiah, ṣé kí a lọ bá Ramoti Gileadi jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?” Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí OLúWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ OLúWA?” Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, OLúWA sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ” Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìre kan sí mi rí bí kò ṣe ibi?” Mikaiah sì tún wí pé, “Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA: Mo rí OLúWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀. OLúWA sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu láti kọlu Ramoti Gileadi? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’ “Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ òmíràn. Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú OLúWA, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ “OLúWA sì béèrè pé, ‘Báwo?’ “Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ̀.’ “OLúWA sì wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, ìwọ yóò sì borí, jáde lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ wọ̀nyí. OLúWA sì ti sọ ibi sí ọ.” Nígbà náà ni Sedekiah ọmọ Kenaana sì dìde, ó sì gbá Mikaiah lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí OLúWA gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” Mikaiah sì wí pé, “Ìwọ yóò rí i ní ọjọ́ náà, nígbà tí ìwọ yóò lọ láti inú ìyẹ̀wù dé ìyẹ̀wù láti fi ara rẹ pamọ́.” Ọba Israẹli sì pàṣẹ pé, “Ẹ mú Mikaiah, kí ẹ sì mú un padà sọ́dọ̀ Amoni, olórí ìlú, àti sọ́dọ̀ Joaṣi ọmọ ọba kí ẹ sì wí pé, ‘Báyìí ni ọba wí: Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà.’ ” Mikaiah sì wí pé, “Bí ìwọ bá padà bọ̀ ní àlàáfíà, OLúWA kò ti ipa mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún wí pé, “Ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo!” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda gòkè lọ sí Ramoti Gileadi. Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. Ọba Aramu ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Israẹli nìkan.” Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jehoṣafati, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Israẹli ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jehoṣafati sì kígbe sókè, àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Israẹli sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.” Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Aramu. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárín kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́. A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀-oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samaria, wọ́n sì sin ín ní Samaria. Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samaria, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn àgbèrè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA ti sọ. Ní ti ìyókù ìṣe Ahabu, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ilé eyín erin tí ó kọ́, àti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Ahabu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Ahasiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ Asa, sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba lórí Juda ní ọdún kẹrin Ahabu ọba Israẹli. Jehoṣafati sì jẹ́ ẹni ọdún márùn-dínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. Ó sì rìn nínú gbogbo ọ̀nà Asa baba rẹ̀, kò sì yípadà kúrò nínú rẹ̀; ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú OLúWA. Kìkì àwọn ibi gíga ni a kò mú kúrò, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí níbẹ̀. Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Israẹli. Ní ti ìyókù ìṣe Jehoṣafati àti ìṣe agbára rẹ̀ tí ó ṣe, àti bí ó ti jagun sí, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ó pa ìyókù àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà ní ọjọ́ Asa baba rẹ̀ run kúrò ní ilẹ̀ náà. Nígbà náà kò sí ọba ní Edomu; adelé kan ni ọba. Jehoṣafati kan ọkọ̀ Tarṣiṣi láti lọ sí Ofiri fún wúrà, ṣùgbọ́n wọn kò lọ: nítorí àwọn ọkọ̀ náà fọ́ ní Esioni-Geberi. Ní ìgbà náà Ahasiah ọmọ Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú ọkọ̀,” ṣùgbọ́n Jehoṣafati kọ̀. Nígbà náà ni Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi, baba rẹ. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ahasiah ọmọ Ahabu bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria ní ọdún kẹtà-dínlógún Jehoṣafati ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ọdún méjì lórí Israẹli. Ó sì ṣe búburú níwájú OLúWA, nítorí tí ó rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀, àti ní ọ̀nà ìyá rẹ̀, àti ní ọ̀nà Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. Ó sì sin Baali, ó sì ń bọ Baali, ó sì mú OLúWA, Ọlọ́run Israẹli bínú, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ ti ṣe.