I. A. Ọba 21:27-29
I. A. Ọba 21:27-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe, Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.
I. A. Ọba 21:27-29 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Elija parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ahabu fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó bọ́ wọn kúrò, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ó gbààwẹ̀, orí aṣọ ọ̀fọ̀ ni ó sì ń sùn; ó sì ń káàkiri pẹlu ìdoríkodò ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. OLUWA tún sọ fún Elija pé, “Ǹjẹ́ o ṣe akiyesi bí Ahabu ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí pé ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ báyìí, n kò ní jẹ́ kí ibi tí mo wí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ kí n tó jẹ́ kí ibi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ̀.”
I. A. Ọba 21:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì gbààwẹ̀. Ó sì dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ń lọ jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé: “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”