I. A. Ọba 21:18-20
I. A. Ọba 21:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀. Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ. Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa.
I. A. Ọba 21:18-20 Yoruba Bible (YCE)
“Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà. Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.” Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?” Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA.
I. A. Ọba 21:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀. Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú OLúWA.