I. A. Ọba 17:7-24
I. A. Ọba 17:7-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na. Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe, Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ. On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu. Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ. On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú. Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ: Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ. O si lọ, o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Elijah: ati on ati obinrin na, ati ile rẹ̀ jẹ li ọjọ pupọ̀. Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni ọmọ obinrin na, iya ile na, ṣe aisàn; aisàn rẹ̀ na si le to bẹ̃, ti kò kù ẹmi ninu rẹ̀. On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ? On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀. O si kepe OLUWA, o si wipe, OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ha mu ibi wá ba opó na pẹlu lọdọ ẹniti emi nṣe atipo, ni pipa ọmọ rẹ̀? On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀. Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji. Elijah si mu ọmọde na, o si mu u sọkalẹ lati inu iyara-òke na wá sinu ile, o si fi i le iya rẹ̀ lọwọ: Elijah si wipe, Wò o, ọmọ rẹ yè. Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.
I. A. Ọba 17:7-24 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà. OLUWA bá tún sọ fún Elija pé, “Dìde nisinsinyii, kí o lọ sí ìlú Sarefati, ní agbègbè Sidoni, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Mo ti pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀ láti máa fún ọ ní oúnjẹ.” Elija bá lọ sí Sarefati. Bí ó ti dé ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà, ó rí obinrin opó kan tí ń wá igi ìdáná. Ó wí fún obinrin yìí pé, “Jọ̀wọ́ lọ bá mi bu omi wá kí n mu.” Bí ó ti ń lọ bu omi náà, Elija tún pè é pada, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́ sí i.” Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.” Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ. Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.” Obinrin yìí bá lọ, ó ṣe bí Elija ti wí. Òun ati Elija ati gbogbo ará ilé rẹ̀ sì ń jẹ àjẹyó fún ọpọlọpọ ọjọ́. Ìyẹ̀fun kò tán ninu ìkòkò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ̀ kò sì gbẹ, bí OLUWA ti ṣèlérí fún un láti ẹnu Elija. Lẹ́yìn èyí, ọmọ obinrin opó yìí ṣàìsàn. Àìsàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọmọ náà ṣàìsí. Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.” Elija dáhùn pé, “Gbé ọmọ náà fún mi.” Ó bá gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e gun orí òkè ilé lọ sinu yàrá tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀. Ó képe OLUWA, ó ní, “OLUWA, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí irú ìdààmú yìí bá obinrin opó tí mò ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yìí, tí o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.” OLUWA dáhùn adura Elija, ẹ̀mí ọmọ náà sì tún pada sinu rẹ̀, ó sì sọjí. Elija gbé ọmọ náà sọ̀kalẹ̀ pada sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó! Ọmọ rẹ ti sọjí.” Obinrin náà sọ fún Elija pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé eniyan Ọlọrun ni ọ́, ati pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA tí ń ti ẹnu rẹ jáde.”
I. A. Ọba 17:7-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ ọ́ wá wí pé: “Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?” Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.” Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí OLúWA Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.” Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ. Nítorí báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí OLúWA yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ” Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti ipa Elijah sọ. Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú. Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?” Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀. Nígbà náà ni ó sì ké pe OLúWA wí pé, “OLúWA Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?” Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe OLúWA pé, “OLúWA Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!” OLúWA sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí. Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!” Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLúWA ní ẹnu rẹ.”