I. A. Ọba 17:21-24
I. A. Ọba 17:21-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀. Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji. Elijah si mu ọmọde na, o si mu u sọkalẹ lati inu iyara-òke na wá sinu ile, o si fi i le iya rẹ̀ lọwọ: Elijah si wipe, Wò o, ọmọ rẹ yè. Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.
I. A. Ọba 17:21-24 Yoruba Bible (YCE)
Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.” OLUWA dáhùn adura Elija, ẹ̀mí ọmọ náà sì tún pada sinu rẹ̀, ó sì sọjí. Elija gbé ọmọ náà sọ̀kalẹ̀ pada sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó! Ọmọ rẹ ti sọjí.” Obinrin náà sọ fún Elija pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé eniyan Ọlọrun ni ọ́, ati pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA tí ń ti ẹnu rẹ jáde.”
I. A. Ọba 17:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe OLúWA pé, “OLúWA Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!” OLúWA sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí. Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!” Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLúWA ní ẹnu rẹ.”