I. A. Ọba 17:2-7
I. A. Ọba 17:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọrọ Oluwa si tọ̀ ọ wá wipe: Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ. O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na. O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
I. A. Ọba 17:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Elija pé, “Kúrò níhìn-ín, kí o doríkọ apá ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara pamọ́ lẹ́bàá odò Keriti, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. Ninu odò yìí ni o óo ti máa bu omi mu, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò kan pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.” Elija bá lọ, ó ṣe bí OLUWA ti wí, ó sì ń gbé ẹ̀bá odò Keriti, ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ ati ẹran wá fún un ní ojoojumọ, ní àràárọ̀ ati ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi odò náà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà.
I. A. Ọba 17:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Elijah wá pé: “Kúrò níhìn-ín, kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani. Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀. Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà. Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà.