I. A. Ọba 13:1-34

I. A. Ọba 13:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

SI kiyesi i, enia Ọlọrun kan lati Juda wá si Beteli nipa ọ̀rọ Oluwa: Jeroboamu duro lẹba pẹpẹ lati fi turari jona. O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ. O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ. Pẹpẹ na si ya, ẽru na si danù kuro ninu pẹpẹ na, gẹgẹ bi àmi ti enia Ọlọrun ti fi fun u nipa ọ̀rọ Oluwa. Ọba si dahùn, o si wi fun enia Ọlọrun na pe, Tù Oluwa Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ́ mi bọ̀ sipo fun mi. Enia Ọlọrun na si tù Ọlọrun loju, a si tun mu ọwọ́ ọba bọ̀ sipo fun u, o si dàbi o ti wà ri. Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ. Enia Ọlọrun na si wi fun ọba pe, Bi iwọ o ba fun mi ni idaji ile rẹ, emi kì yio ba ọ lọ ile, emi kì yio si jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kì yio si mu omi nihin yi. Nitori bẹ̃ li a pa a laṣẹ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Máṣe jẹ onjẹ, má si ṣe mu omi, bẹ̃ni ki o má si ṣe pada li ọ̀na kanna ti o ba wá. Bẹ̃ li o si ba ọ̀na miran lọ, kò si pada li ọ̀na na ti o gbà wá si Beteli. Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn. Baba wọn si wi fun wọn pe, Ọna wo li o gbà? Nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti ri ọ̀na ti enia Ọlọrun na gbà, ti o ti Juda wá. O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u o si gùn u. O si tẹ̀le enia Ọlọrun na lẹhin, o si ri i, o joko labẹ igi nla kan: o si wi fun u pe, Iwọ ni enia Ọlọrun na ti o ti Juda wá? On si wipe, Emi ni. O si wi fun u pe, Ba mi lọ ile, ki o si jẹ onjẹ. On si wipe, Emi kò lè pada lọ pẹlu rẹ, bẹ̃ni emi kò lè ba ọ lọ: bẹ̃ni emi kì o jẹ onjẹ, emi kì o si mu omi pẹlu rẹ nihin yi. Nitori ti a sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Iwọ kò gbọdọ jẹ onjẹ, iwọ kò si gbọdọ mu omi nibẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tun pada lọ nipa ọ̀na ti iwọ ba wá. O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u. Bẹ̃ li o si ba a pada lọ, o si jẹ onjẹ ni ile rẹ̀, o si mu omi. O si ṣe, bi nwọn ti joko ti tabili, li ọ̀rọ Oluwa tọ woli na wá ti o mu u padà bọ̀: O si kigbe si enia Ọlọrun ti o ti Juda wá wipe, bayi li Oluwa wi: Niwọn bi iwọ ti ṣe aigbọran si ẹnu Oluwa, ti iwọ kò si pa aṣẹ na mọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ pa fun ọ. Ṣugbọn iwọ pada, iwọ si ti jẹ onjẹ, iwọ si ti mu omi ni ibi ti Oluwa sọ fun ọ pe, Máṣe jẹ onjẹ, ki o má si ṣe mu omi; okú rẹ kì yio wá sinu iboji awọn baba rẹ. O si ṣe, lẹhin igbati o ti jẹ onjẹ, ati lẹhin igbati o ti mu, li o di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u, eyini ni, fun woli ti o ti mu pada bọ̀. Nigbati o si lọ tan, kiniun kan pade rẹ̀ li ọ̀na, o si pa a: a si gbe okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, kẹtẹkẹtẹ si duro tì i, kiniun pẹlu duro tì okú na. Si kiyesi i, awọn enia nkọja, nwọn ri pe, a gbe okú na sọ si oju ọ̀na, kiniun na si duro tì okú na: nwọn si wá, nwọn si sọ ọ ni ilu ti woli àgba na ngbe. Nigbati woli ti o mu u lati ọ̀na pada bọ̀ gbọ́, o wipe, Enia Ọlọrun na ni, ti o ṣọ̀tẹ si Oluwa: nitorina li Oluwa fi i le kiniun lọwọ, ti o si fà a ya, ti o si pa a, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ fun u. O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di i ni gari. O si lọ, o si ri, a gbé okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, ati kẹtẹkẹtẹ, ati kiniun duro ti okú na, kiniun kò jẹ okú na, bẹ̃ni kò fà kẹtẹkẹtẹ na ya. Woli na mu okú enia Ọlọrun na, o si gbé e lori kẹtẹkẹtẹ na, o si mu u pada bọ̀: woli àgba na si wá si ilu, lati ṣọ̀fọ, ati lati sin i. O si tẹ okú rẹ̀ sinu iboji ara rẹ̀: nwọn si sọ̀fọ lori rẹ̀, pe: O ṣe, arakunrin mi! O si ṣe, lẹhin igbati o ti sinkú rẹ̀ tan, o si sọ fun awọn ọmọ rẹ̀ wipe, Nigbati mo ba kú, nigbana ni ki ẹ sinkú mi ni iboji ninu eyiti a sin enia Ọlọrun; ẹ tẹ́ egungun mi lẹba egungun rẹ̀: Nitori ni ṣiṣẹ, ọ̀rọ ti o kigbe nipa ọ̀rọ Oluwa si pẹpẹ na ni Beteli, ati si gbogbo ile ibi giga ti mbẹ ni gbogbo ilu Samaria, yio ṣẹ dandan. Lẹhin nkan yi, Jeroboamu kò pada kuro ninu ọ̀na ibi rẹ̀, ṣugbọn o tun mu ninu awọn enia ṣe alufa ibi giga wọnni: ẹnikẹni ti o ba fẹ, a yà a sọtọ̀ on a si di alufa ibi giga wọnni. Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ani lati ke e kuro, ati lati pa a run kuro lori ilẹ.

I. A. Ọba 13:1-34 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA pàṣẹ fún wolii kan, ará Juda, pé kí ó lọ sí Bẹtẹli; nígbà tí ó débẹ̀ ó bá Jeroboamu tí ó dúró níwájú pẹpẹ láti sun turari. Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ” Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.” Nígbà tí Jeroboamu gbọ́ ìkìlọ̀ tí wolii Ọlọrun yìí ṣe fún pẹpẹ náà, ó na ọwọ́ sí wolii náà láti ibi pẹpẹ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ ọba bá gan, kò sì lè gbé e wálẹ̀ mọ́. Pẹpẹ náà wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ sì fọ́n dànù gẹ́gẹ́ bí wolii náà ti sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA. Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.” Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ọba bá sọ fún wolii náà pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé mi kí o lọ jẹun, n óo sì fún ọ ní ẹ̀bùn fún ohun tí o ṣe fún mi.” Ṣugbọn wolii náà dáhùn pé, “Bí o bá tilẹ̀ fẹ́ fún mi ní ìdajì ohun tí o ní, n kò ní bá ọ lọ, n kò ní fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí. Nítorí pé, OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé n kò gbọdọ̀ fẹnu kan nǹkankan ati pé, n kò gbọdọ̀ gba ọ̀nà tí mo gbà wá pada.” Nítorí náà, kò gba ọ̀nà ibi tí ó gbà wá pada, ọ̀nà ibòmíràn ni ó gbà lọ. Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba. Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án. Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni. Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.” Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí. Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.” Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.” Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀. Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀. Ó bá kígbe mọ́ wolii ará Juda yìí, ó ní, “OLUWA ní, nítorí pé o ti ṣe àìgbọràn sí òun, o kò sì ṣe ohun tí òun OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, o pada, o jẹ, o sì mu ní ibi tí òun ti pàṣẹ pé o kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan. Nítorí náà, o óo kú, wọn kò sì ní sin òkú rẹ sinu ibojì àwọn baba rẹ.” Nígbà tí wọ́n jẹun tan, wolii àgbàlagbà yìí di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì fún wolii ará Juda. Wolii ará Juda náà bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó ń lọ. Bí ó ti ń lọ lójú ọ̀nà, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Òkú rẹ̀ wà ní ojú ọ̀nà níbẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà sì dúró tì í. Àwọn ọkunrin kan tí wọn ń kọjá lọ rí òkú ọkunrin yìí lójú ọ̀nà, ati kinniun tí ó dúró tì í. Wọ́n lọ sí ìlú Bẹtẹli níbi tí wolii àgbàlagbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ohun tí wọ́n rí fún un. Nígbà tí wolii àgbàlagbà náà gbọ́, ó ní, “Wolii tí ó ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ OLUWA ni. Nítorí náà ni OLUWA fi rán kinniun sí i, pé kí ó pa á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti kìlọ̀ fún un tẹ́lẹ̀.” Ó bá pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.” Wọ́n sì bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun. Wolii àgbàlagbà yìí gbé òkú ọkunrin náà sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì gbé e pada wá sí ìlú Bẹtẹli láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ati láti sin ín. Ninu ibojì tirẹ̀ gan-an ni ó sin ín sí. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ó ṣe, arakunrin mi! Arakunrin mi!” Lẹ́yìn ìsìnkú náà, wolii àgbàlagbà yìí sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kú, inú ibojì kan náà ni kí wọn ó sin òun sí, ati pé ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gan-an ni kí wọ́n tẹ́ òkú òun sí. Ó ní, “Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ ìbáwí tí OLUWA pàṣẹ pé kí ó sọ sí pẹpẹ Bẹtẹli, ati gbogbo pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà káàkiri ní àwọn ìlú Samaria yóo ṣẹ.” Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Jeroboamu, ọba Israẹli kò yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀. Ṣugbọn ó ń yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú láàrin àwọn eniyan ó sì ń fi wọ́n jẹ alufaa ní àwọn ibi pẹpẹ ìrúbọ káàkiri. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohun tí ó ṣe yìí, ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni ó sì run ìran rẹ̀ lórí oyè, tí wọ́n fi parun patapata lórílẹ̀ ayé.

I. A. Ọba 13:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ OLúWA, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ OLúWA wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni OLúWA wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní ààmì kan wí pé: “Èyí ni ààmì tí OLúWA ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.” Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ààmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ OLúWA. Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú OLúWA Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ OLúWA, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.” Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ OLúWA wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli. Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Beteli, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Beteli ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba. Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ọ̀nà wo ni ó gbà?” Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Juda gbà hàn án. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún. Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn. Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi óákù kan, ó sì wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá bí?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, “Bá mi lọ ilé, kí o sì jẹun.” Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, “Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn-ín. A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ OLúWA pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’ ” Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Angẹli sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ OLúWA pé: ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.) Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀. Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé; Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni OLúWA wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ OLúWA jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́. Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ” Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un. Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́. Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí pé ó gbé òkú náà sọ sí ojú ọ̀nà, kìnnìún náà sì dúró ti òkú náà; wọ́n sì wá, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé. Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ OLúWA jẹ́. OLúWA sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti kìlọ̀ fún un.” Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!” Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀. Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ OLúWA sí pẹpẹ tí ó wà ní Beteli àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samaria yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.” Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jeroboamu kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí. Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.