I. A. Ọba 12:1-5
I. A. Ọba 12:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o wà ni Egipti sibẹ gbọ́, nitori ti o ti sá kuro niwaju Solomoni ọba, Jeroboamu si joko ni Egipti. Nwọn si ranṣẹ pè e, ati Jeroboamu ati gbogbo ijọ Israeli wá, nwọn si sọ fun Rehoboamu wipe, Baba rẹ sọ àjaga wa di wuwo: njẹ nitorina, ṣe ki ìsin baba rẹ ti o le, ati àjaga rẹ̀ ti o wuwo, ti o fi si wa li ọrùn, ki o fẹrẹ̀ diẹ, awa o si sìn ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ na titi di ijọ mẹta, nigbana ni ki ẹ pada tọ̀ mi wá. Awọn enia na si lọ.
I. A. Ọba 12:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ níbẹ̀ láti fi jọba. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ìròyìn yìí ní Ijipti, (níbẹ̀ ni ó ń gbé láti ìgbà tí ó ti sá lọ fún Solomoni ọba), ó pada wá sílé láti Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ pè é, òun ati gbogbo wọ́n sì tọ Rehoboamu lọ, wọ́n wí fún un pé, “Àjàgà wúwo ni Solomoni baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn. Ṣugbọn bí o bá dín iṣẹ́ líle baba rẹ yìí kù, tí o sì mú kí ìgbé ayé rọ̀ wá lọ́rùn, a óo máa sìn ọ́.” Rehoboamu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ná, lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, ẹ pada wá gbọ́ èsì.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ.
I. A. Ọba 12:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé: “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.” Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.