I. A. Ọba 11:13-43

I. A. Ọba 11:13-43 Bibeli Mimọ (YBCV)

Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn. Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu. O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu. Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu: Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde. Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ. Hadadi si ri oju-rere pupọ̀ niwaju Farao, o si fun u li arabinrin aya rẹ̀, li aya, arabinrin Tapenesi, ayaba. Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao, Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi. Nigbana ni Farao wi fun u pe, ṣugbọn kini iwọ ṣe alaini lọdọ mi, si kiyesi i, iwọ nwá ọ̀na lati lọ si ilu rẹ? O si wipe: Kò si nkan: ṣugbọn sa jẹ ki emi ki o lọ. Pẹlupẹlu Ọlọrun gbe ọta dide si i; ani Resoni, ọmọ Eliada, ti o ti sá kuro lọdọ Hadadeseri oluwa rẹ̀, ọba Soba: On si ko enia jọ sọdọ ara rẹ̀, o si di olori-ogun ẹgbẹ́ kan, nigbati Dafidi fi pa wọn, nwọn si lọ si Damasku, nwọn ngbe ibẹ, nwọn si jọba ni Damasku. On si ṣe ọta si Israeli ni gbogbo ọjọ Solomoni, lẹhin ibi ti Hadadi ṣe: Resoni si korira Israeli, o si jọba lori Siria. Ati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ara Efrati ti Sereda, iranṣẹ Solomoni, orukọ iya ẹniti ijẹ Serua, obinrin opó kan, on pẹlu gbe ọwọ soke si ọba. Eyi si ni idi ohun ti o ṣe gbe ọwọ soke si ọba: Solomoni kọ́ Millo, o si di ẹya ilu Dafidi baba rẹ̀. Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu. O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko: Ahijah si gbà agbáda titun na ti o wà lara rẹ̀, o si fà a ya si ọ̀na mejila: O si wi fun Jeroboamu pe, Iwọ mu ẹya mẹwa: nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o fa ijọba na ya kuro li ọwọ Solomoni, emi o si fi ẹya mẹwa fun ọ. Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli: Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́: Ṣugbọn emi o gba ijọba na li ọwọ ọmọ rẹ̀, emi o si fi i fun ọ, ani ẹya mẹwa. Emi o si fi ẹya kan fun ọmọ rẹ̀, ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ. Emi o si mu ọ, iwọ o si jọba gẹgẹ bi gbogbo eyiti ọkàn rẹ nfẹ, iwọ o si jẹ ọba lori Israeli. Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ. Emi o si pọ́n iru-ọmọ Dafidi loju nitori eyi, ṣugbọn kì iṣe titi lai. Nitorina Solomoni wá ọ̀na lati pa Jeroboamu. Jeroboamu si dide, o si sá lọ si Egipti si ọdọ Ṣiṣaki ọba Egipti, o si wà ni Egipti titi ikú Solomoni. Ati iyokù iṣe Solomoni ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe iṣe Solomoni bi? Ọjọ ti Solomoni jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli jẹ ogoji ọdun. Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

I. A. Ọba 11:13-43 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn n kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, n óo ṣẹ́ ẹ̀yà kan kù sí ọmọ rẹ lọ́wọ́, nítorí ti Dafidi iranṣẹ mi ati ìlú Jerusalẹmu tí mo ti yàn.” OLUWA bá mú kí Adadi dojú ọ̀tá kọ Solomoni; Adadi yìí jẹ́ ìran ọba ní ilẹ̀ àwọn ará Edomu. Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu; nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run. Ṣugbọn Adadi ati díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ baba rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Edomu sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Adadi kéré pupọ nígbà náà. Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé. Adadi bá ojurere Farao ọba pàdé, ọba bá fi arabinrin ayaba Tapenesi, iyawo rẹ̀, fún Adadi kí ó fi ṣe aya. Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba. Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.” Farao bá bi í léèrè pé, “Kí lo fẹ́ tí o kò rí lọ́dọ̀ mi, tí o fi fẹ́ máa lọ sí ìlú rẹ?” Ṣugbọn Adadi dá a lóhùn pé, “Ṣá jẹ́ kí n máa lọ.” Ọlọrun tún mú kí Resoni ọmọ Eliada dojú ọ̀tá kọ Solomoni, sísá ni Resoni yìí sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri, ọba Soba, tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku. Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀. Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí: Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́, ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu. Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá. Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila. Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Nítorí pé, Solomoni ti kọ òun sílẹ̀, ó sì ń bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni; ati Kemoṣi, oriṣa àwọn ará Moabu; ati Milikomu oriṣa àwọn ará Amoni. Solomoni kò máa rìn ní ọ̀nà òun OLUWA, kí ó máa ṣe rere, kí ó máa pa òfin òun mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé ìlànà òun bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Sibẹsibẹ ó ní òun kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Solomoni, òun óo fi sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ẹni tí òun yàn, tí ó pa òfin òun mọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà òun. Ṣugbọn òun óo gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ Solomoni, òun óo sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá. Òun óo fi ẹ̀yà kan sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, kí ọ̀kan ninu arọmọdọmọ Dafidi, iranṣẹ òun, lè máa jọba nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí òun ti yàn fún ìjọ́sìn ní orúkọ òun. Ó ní ìwọ Jeroboamu ni òun óo mú, tí òun óo sì fi jọba ní Israẹli, o óo sì máa jọba lórí gbogbo agbègbè tí ó bá wù ọ́. Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ. Ó ní òun óo jẹ arọmọdọmọ Dafidi níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Solomoni, ṣugbọn kò ní jẹ́ títí ayé.” Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, Solomoni ń wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣugbọn Jeroboamu sá lọ sọ́dọ̀ Ṣiṣaki, ọba Ijipti, níbẹ̀ ni ó sì wà títí tí Solomoni fi kú. Àwọn nǹkan yòókù tí Solomoni ṣe: gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ati ọgbọ́n rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìṣe Solomoni. Ogoji ọdún ni ó fi jọba lórí gbogbo Israẹli ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

I. A. Ọba 11:13-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jerusalẹmu tí èmi ti yàn.” Nígbà náà ni OLúWA gbé ọ̀tá kan dìde sí Solomoni, Hadadi ará Edomu ìdílé ọba ni ó ti wá ní Edomu. Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu. Nítorí Joabu àti gbogbo Israẹli sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Edomu run. Ṣùgbọ́n Hadadi sálọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ará Edomu tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ baba rẹ̀. Hadadi sì wà ní ọmọdé nígbà náà. Wọ́n sì dìde kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Parani wá, wọ́n sì lọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Farao ọba Ejibiti ẹni tí ó fún Hadadi ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ. Inú Farao sì dùn sí Hadadi púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tapenesi, ayaba. Arábìnrin Tapenesi bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Genubati, ẹni tí Tapenesi tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Genubati ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Farao fúnrarẹ̀. Nígbà tí ó sì wà ní Ejibiti, Hadadi sì gbọ́ pé Dafidi ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Joabu olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hadadi wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.” Farao sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?” Hadadi sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!” Ọlọ́run sì gbé ọ̀tá mìíràn dìde sí Solomoni, Resoni ọmọ Eliada, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri olúwa rẹ̀, ọba Ṣoba. Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dafidi fi pa ogun Ṣoba run; wọ́n sì lọ sí Damasku, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jẹ ọba ní Damasku. Resoni sì jẹ́ ọ̀tá Israẹli ní gbogbo ọjọ́ Solomoni, ó ń pa kún ibi ti Hadadi ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Resoni jẹ ọba ní Siria, ó sì ṣòdì sí Israẹli. Bákan náà Jeroboamu ọmọ Nebati sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Solomoni, ará Efraimu ti Sereda, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Serua. Èyí sì ni ìdí tí ó fi ṣọ̀tẹ̀ sí ọba: Solomoni kọ́ Millo, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jeroboamu jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Solomoni sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Josẹfu. Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jeroboamu ń jáde kúrò ní Jerusalẹmu. Wòlíì Ahijah ti Ṣilo sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá tuntun. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko, Ahijah sì gbá agbádá tuntun tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá Nígbà náà ni ó sọ fún Jeroboamu pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Solomoni, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. Ṣùgbọ́n nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, òun yóò ní ẹ̀yà kan. Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni, Kemoṣi òrìṣà àwọn ará Moabu, àti Moleki òrìṣà àwọn ọmọ Ammoni, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dafidi baba Solomoni ti ṣe. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Solomoni; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́. Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dafidi ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jẹ ọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́; ìwọ yóò jẹ ọba lórí Israẹli. Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dafidi ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dafidi, èmi yóò sì fi Israẹli fún ọ. Èmi yóò sì rẹ irú-ọmọ Dafidi sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé.’ ” Solomoni wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣùgbọ́n Jeroboamu sálọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Ṣiṣaki ọba Ejibiti, ó sì wà níbẹ̀ títí Solomoni fi kú. Ìyókù iṣẹ́ Solomoni àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Solomoni bí? Solomoni sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli ní ogójì ọdún. Nígbà náà ni Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Rehoboamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.