I. A. Ọba 11:1-8
I. A. Ọba 11:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ àwọn obinrin àjèjì ni Solomoni fẹ́, lẹ́yìn ọmọ Farao, ọba Ijipti, tí ó kọ́kọ́ fẹ́, ó tún fẹ́ ará Moabu ati ará Amoni, ará Edomu ati ará Sidoni, ati ará Hiti. Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí Solomoni di àgbàlagbà, àwọn iyawo rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ó ń bọ àwọn oriṣa àjèjì, kò sì ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ mọ́, bíi Dafidi, baba rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni ati oriṣa Milikomu, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ. Ohun tí Solomoni ṣe burú lójú OLUWA, kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ̀. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ kan sí orí òkè ní ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu fún oriṣa Kemoṣi, ohun ìríra tí àwọn ará Moabu ń bọ, ati fún oriṣa Moleki, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn.
I. A. Ọba 11:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Farao, àwọn ọmọbìnrin Moabu, àti ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni àti ti àwọn ọmọ Hiti. Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí OLúWA ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe búburú níwájú OLúWA; kò sì tọ OLúWA lẹ́yìn ní pípé, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn.
I. A. Ọba 11:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN Solomoni ọba fẹràn ọ̀pọ ajeji obinrin, pẹlu ọmọbinrin Farao, awọn obinrin ara Moabu, ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni ati ti awọn ọmọ Hitti. Awọn orilẹ-ède ti Oluwa wi fun awọn ọmọ-Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ wọle tọ̀ wọn, bẹ̃ni awọn kò gbọdọ wọle tọ̀ nyin: nitõtọ nwọn o yi nyin li ọkàn pada si oriṣa wọn: Solomoni fà mọ awọn wọnyi ni ifẹ. O si ni ẽdẹgbẹrin obinrin, awọn ọmọ ọba, ati ọ̃dunrun alè, awọn aya rẹ̀ si yi i li ọkàn pada. O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀. Nitori Solomoni tọ Aṣtoreti lẹhin, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Milkomu, irira awọn ọmọ Ammoni. Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni. Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn.