I. A. Ọba 1:28-53

I. A. Ọba 1:28-53 Bibeli Mimọ (YBCV)

Dafidi, ọba si dahùn o si wipe, Ẹ pè Batṣeba fun mi. On si wá siwaju ọba, o si duro niwaju ọba, Ọba si bura, o si wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹniti o ti rà ọkàn mi pada kuro ninu gbogbo ìṣẹ́. Gẹgẹ bi mo ti fi Oluwa, Ọlọrun Israeli bura fun ọ, wipe, Nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi ni ipò mi, bẹ̃ni emi o ṣe loni yi dandan. Batṣeba si foribalẹ, o si bọ̀wọ fun ọba, o si wipe, Ki oluwa mi, Dafidi ọba ki o pẹ titi lai. Dafidi ọba wipe, Ẹ pè Sadoku alufa fun mi, ati Natani woli, ati Benaiah ọmọ Jehoiada. Nwọn si wá siwaju ọba. Ọba si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn iranṣẹ oluwa nyin, ki ẹ si mu ki Solomoni ọmọ mi ki o gùn ibãka mi, ki ẹ si mu sọkalẹ wá si Gihoni. Ki ẹ si jẹ ki Sadoku, alufa, ati Natani woli, fi ororo yàn a nibẹ̀ li ọba lori Israeli: ki ẹ si fun fère, ki ẹ si wipe; Ki Solomoni ọba ki o pẹ! Ki ẹ si goke tọ̀ ọ lẹhin, ki o si wá, ki o si joko lori itẹ mi; on o si jọba ni ipò mi: emi si pa a laṣẹ lati jẹ olori Israeli ati Juda. Benaiah ọmọ Jehoiada, si da ọba lohùn, o si wipe, Amin: Oluwa, Ọlọrun ọba oluwa mi, wi bẹ̃ pẹlu. Bi Oluwa ti wà pẹlu oluwa mi ọba, gẹgẹ bẹ̃ni ki o wà pẹlu Solomoni, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ oluwa mi, Dafidi ọba lọ. Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti si sọkalẹ, nwọn si mu ki Solomoni ki o gùn ibãka Dafidi ọba, nwọn si mu u wá si Gihoni, Sadoku alufa si mu iwo ororo lati inu agọ, o si dà a si Solomoni lori; nwọn si fun fère; gbogbo enia si wipe, Ki Solomoni ọba ki o pẹ. Gbogbo enia si goke tọ̀ ọ lẹhin, awọn enia si fun ipè, nwọn si yọ̀ ayọ̀ nlanla, tobẹ̃ ti ilẹ mì fun iró wọn. Ati Adonijah ati gbogbo awọn ti o pè sọdọ rẹ̀ si gbọ́, nigbati nwọn jẹun tan, Joabu si gbọ́ iró ipè o si wipe: eredi ariwo ilu ti nrọkẹkẹ yi? Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufa de; Adonijah si wi fun u pe, Mã wolẹ̀; nitoripe alagbara ọkunrin ni iwọ, ati ẹniti nmu ihin-rere wá. Jonatani si dahùn o si wi fun Adonijah pe, Lõtọ ni, oluwa wa, Dafidi ọba, fi Solomoni jọba. Ọba si ti rán Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti pẹlu rẹ̀, nwọn si ti mu u ki o gùn ibãka ọba. Sadoku, alufa ati Natani, woli si ti fi ororo yàn a li ọba ni Gihoni: nwọn si fi ayọ̀ goke lati ibẹ wá, tobẹ̃ ti ilu si nho. Eyi ni ariwo ti ẹ ti gbọ́. Solomoni si joko lori itẹ ijọba pẹlu. Awọn iranṣẹ ọba si wá lati sure fun oluwa wa, Dafidi ọba, pe, Ki Ọlọrun ki o mu orukọ Solomoni ki o sàn jù orukọ rẹ lọ, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ rẹ lọ. Ọba si gbadura lori akete. Ọba si wi bayi pẹlu, Olubukun li Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fun mi li ẹnikan ti o joko lori itẹ mi loni, oju mi si ri i. Gbogbo awọn ti a pè, ti nwọn wà li ọdọ Adonijah si bẹ̀ru, nwọn si dide, nwọn si lọ olukuluku si ọ̀na rẹ̀. Adonijah si bẹ̀ru Solomoni, o si dide, o si lọ, o si di iwo pẹpẹ mu. Nwọn si wi fun Solomoni pe, Wò o, Adonijah bẹ̀ru Solomoni ọba: si kiyesi i, o di iwo pẹpẹ mu, o nwipe, Ki Solomoni ọba ki o bura fun mi loni pe, On kì yio fi idà pa iranṣẹ rẹ̀. Solomoni si wipe, Bi o ba jẹ fi ara rẹ̀ si ọ̀wọ, irun ori rẹ̀ kan kì yio bọ́ silẹ: ṣugbọn bi a ba ri buburu lọwọ rẹ̀, on o kú. Solomoni ọba si ranṣẹ, nwọn mu u sọkalẹ lori pẹpẹ. On si wá, o si foribalẹ̀ fun Solomoni ọba: Solomoni si wi fun u pe, Mã lọ ile rẹ.

I. A. Ọba 1:28-53 Yoruba Bible (YCE)

Dafidi ọba bá ní kí wọ́n pe Batiṣeba pada wọlé. Ó bá pada wá siwaju ọba. Ọba bá búra fún un pé, “Mo ṣe ìlérí fún ọ ní orúkọ OLUWA Alààyè, tí ó gbà mí ninu gbogbo ìyọnu mi, pé lónìí ni n óo mú ìbúra tí mo búra fún ọ ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣẹ, pé, Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn mi.” Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.” Ọba bá ranṣẹ pe Sadoku, alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, gbogbo wọ́n sì pésẹ̀ sọ́dọ̀ ọba. Ọba bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ mi lẹ́yìn, kí ẹ sì gbé Solomoni gun ìbaaka mi, kí ẹ mú un lọ sí odò Gihoni, kí Sadoku, alufaa ati Natani wolii, fi àmì òróró yàn án ní ọba níbẹ̀, lórí gbogbo Israẹli. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì hó pé, ‘Kí ẹ̀mí Solomoni, ọba, kí ó gùn!’ Lẹ́yìn náà, ẹ óo tẹ̀lé e pada wá síhìn-ín kí ó wá jókòó lórí ìtẹ́ mi; nítorí pé òun ni yóo jọba lẹ́yìn mi. Òun ni mo yàn láti jọba Israẹli ati Juda.” Bẹnaya bá dáhùn pé, “Àṣẹ! Kí OLUWA Ọlọrun rẹ bá wa lọ́wọ́ sí i. Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.” Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni. Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.” Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì. Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?” Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.” Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba! Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba. Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo. Solomoni ti gúnwà lórí ìtẹ́ ọba. Kí ló tún kù! Gbogbo àwọn iranṣẹ ọba ni wọ́n ti lọ kí Dafidi ọba, pé, ‘Kí Ọlọrun rẹ mú kí Solomoni lókìkí jù ọ́ lọ, kí ìjọba rẹ̀ sì ju tìrẹ lọ.’ Ọba bá tẹríba, ó sì sin Ọlọrun lórí ibùsùn rẹ̀, ó ní ‘Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi jọba lónìí, tí ó sì jẹ́ kí n fi ojú mi rí i.’ ” Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí wọ́n lọ bá Adonija jẹ àsè, gbogbo wọ́n bá dìde, olukuluku bá tirẹ̀ lọ. Ẹ̀rù Solomoni ba Adonija tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, tí ó sì di ìwo pẹpẹ mú. Wọ́n sọ fún Solomoni ọba pé ẹ̀rù rẹ ń ba Adonija ati pé ó wà níbi tí ó ti di ìwo pẹpẹ mú, tí ó sì wí pé, àfi kí Solomoni ọba fi ìbúra ṣèlérí pé kò ní pa òun. Solomoni dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ olóòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní fi ọwọ́ kan ẹyọ kan ninu irun orí rẹ̀, ṣugbọn bí ó bá hùwà ọ̀tẹ̀, yóo kú.” Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀.

I. A. Ọba 1:28-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Dafidi ọba wí pé, “Pe Batṣeba wọlé wá.” Ó sì wá síwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀. Ọba sì búra pé, “Dájúdájú bí OLúWA ti wà ẹni tí ó ti gbà mí kúrò nínú gbogbo wàhálà, Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi OLúWA Ọlọ́run Israẹli búra fún yọ pé: Solomoni ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.” Nígbà náà ni Batṣeba tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí olúwa mi Dafidi ọba kí ó pẹ́!” Dafidi ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadoku àlùfáà wọlé fún mi àti Natani wòlíì àti Benaiah ọmọ Jehoiada.” Nígbà tí wọ́n wá síwájú ọba, Ọba sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Solomoni ọmọ mi kí ó gun ìbáaka mi, kí ẹ sì mú un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gihoni. Níbẹ̀ ni Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì yóò ti fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!’ Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jẹ ọba ní ipò mi. Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Israẹli àti Juda.” Benaiah ọmọ Jehoiada sì dá ọba lóhùn pé, “Àmín! Kí OLúWA Ọlọ́run olúwa mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀ Bí OLúWA ti wà pẹ̀lú olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Solomoni kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ olúwa mi Dafidi ọba lọ!” Nígbà náà ni Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada, àwọn ará Kereti àti Peleti sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Solomoni gun ìbáaka Dafidi ọba wá sí Gihoni. Sadoku àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Solomoni lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!” Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn. Adonijah àti gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ìpè, Joabu sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?” Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jonatani ọmọ Abiatari àlùfáà sì dé, Adonijah sì wí pé, “Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọdọ̀ mú ìròyìn rere wá.” Jonatani sì dáhùn, ó sì wí fún Adonijah pé, “Lóòótọ́ ni olúwa wa Dafidi ọba, fi Solomoni jẹ ọba. Ọba sì ti rán Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada àti àwọn ará Kereti àti Peleti pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbáaka ọba, Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gihoni. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́. Solomoni sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá olúwa wa Dafidi ọba yọ̀, wí pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Solomoni lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ!’ Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀, ọba sì wí pé, ‘Ògo ni fún OLúWA Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ” Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Adonijah dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká. Ṣùgbọ́n Adonijah sì bẹ̀rù Solomoni, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. Nígbà náà ni a sì sọ fún Solomoni pé, “Adonijah bẹ̀rù Solomoni ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí ọba Solomoni búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’ ” Solomoni sì dáhùn pé, “Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú.” Nígbà náà ni Solomoni ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá. Adonijah sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Solomoni ọba, Solomoni sì wí pé, “Lọ ilé rẹ.”