I. Joh 4:4-6
I. Joh 4:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ. Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn. Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.
I. Joh 4:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ. Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn. Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí.
I. Joh 4:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn. Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.