I. Joh 4:2-4
I. Joh 4:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni: Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye. Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ.
I. Joh 4:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí kò bá jẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọrun. Alátakò Kristi tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti dé inú ayé nisinsinyii. Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ.
I. Joh 4:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni: Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé. Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ.