I. Joh 4:19-21
I. Joh 4:19-21 Yoruba Bible (YCE)
A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọrun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí. Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu.
I. Joh 4:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa. Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri? Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.
I. Joh 4:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, “Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run,” tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni: nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí? Òfin yìí ni àwa sì rí gbà láti ọwọ́ rẹ̀ wá, pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.