I. Joh 4:12-19
I. Joh 4:12-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye. Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun. Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀. Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi. Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ. Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa.
I. Joh 4:12-19 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa. A mọ̀ pé à ń gbé inú Ọlọrun ati pé òun náà ń gbé inú wa nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu, Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀, òun náà sì ń gbé inú Ọlọrun. A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe di pípé ninu wa, kí á lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ pé bí ó ti rí ni àwa náà rí ninu ayé yìí. Kò sí ẹ̀rù ninu ìfẹ́; ìfẹ́ pípé a máa lé ẹ̀rù jáde, nítorí ìjayà ni ó ń mú ẹ̀rù wá. Ẹni tí ó bá ń bẹ̀rù kò ì tíì di pípé ninu ìfẹ́. A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọrun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.
I. Joh 4:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnikẹ́ni kò ri Ọlọ́run nígbà kan rí. Bí àwa bá fẹ́ràn ara wa, Ọlọ́run ń gbé inú wa, a sì mú ìfẹ́ rẹ̀ pé nínú wa. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń gbé inú rẹ̀, àti Òun nínú wa, nítorí tí ó ti fi Ẹ̀mí rẹ̀ fún wa. Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run. Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́. Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.