I. Joh 2:3-6
I. Joh 2:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba npa ofin rẹ̀ mọ́, lara rẹ̀ li a gbé mu ifẹ Ọlọrun pé nitõtọ. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mbẹ ninu rẹ̀, Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on na pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹ bi on ti rìn.
I. Joh 2:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀. Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé.
I. Joh 2:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.