I. Joh 2:27
I. Joh 2:27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀.
Pín
Kà I. Joh 2I. Joh 2:27 Yoruba Bible (YCE)
ẹ jẹ́ kí òróró tí Jesu ta si yín lórí máa gbé inú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí òróró rẹ̀ ninu yín ti ń kọ yín nípa ohun gbogbo, òtítọ́ ni, kì í ṣe irọ́, ẹ máa gbé inú rẹ̀, bí ó ti kọ yín.
Pín
Kà I. Joh 2I. Joh 2:27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ní ti ìfóróróyàn tí ẹ̀yín gba lọ́wọ́ rẹ̀ ṣì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín. Ṣùgbọ́n bí ìfòróróyàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí ó jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀.
Pín
Kà I. Joh 2