I. Joh 2:18-29

I. Joh 2:18-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi. Nwọn ti ọdọ wa jade, ṣugbọn nwọn ki iṣe ará wa; nitori nwọn iba ṣe ará wa, nwọn iba bá wa duro: ṣugbọn nwọn jade ki a le fi wọn hàn pe gbogbo nwọn ki iṣe ará wa. Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo. Emi kò kọwe si nyin nitoripe ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ninu otitọ. Tani eke, bikoṣe ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Aṣodisi-Kristi, ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ. Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu. Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba. Eyi si ni ileri na ti o ti ṣe fun wa, ani ìye ainipẹkun. Nkan wọnyi ni mo kọwe si nyin niti awọn ti ntàn nyin jẹ. Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀. Ati nisisiyi, ẹnyin ọmọ mi, ẹ mã gbe inu rẹ̀; pe, nigbati on o ba farahàn, ki a le ni igboiya niwaju rẹ̀, ki oju má si tì wa niwaju rẹ̀ ni igba wiwá rẹ̀. Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo ni on, ẹ mọ̀ pe a bi olukuluku ẹniti nṣe ododo nipa rẹ̀.

I. Joh 2:18-29 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí. Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti kúrò ṣugbọn wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ara wa ni wọ́n, wọn ìbá dúró lọ́dọ̀ wa. Ṣugbọn kí ó lè hàn dájú pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa ni wọ́n ṣe kúrò lọ́dọ̀ wa. Ẹ̀yin ni Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi òróró yàn, gbogbo yín sì mọ òtítọ́. Kì í ṣe pé ẹ kò mọ òtítọ́ ni mo ṣe kọ ìwé si yín, ṣugbọn nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n ni, kò sí irọ́ kankan tí ó lè jáde láti inú òtítọ́. Ta ni òpùrọ́ bí ẹni tí ó bá kọ̀ láti gbà pé Jesu ni Mesaya? Olúwarẹ̀ ni Alátakò Kristi, tí ó kọ Baba ati Ọmọ. Ẹni tí ó bá kọ Ọmọ kò ní Baba. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ Ọmọ ní Baba pẹlu. Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ máa gbé inú yín. Bí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin yóo máa gbé inú Ọmọ ati Baba. Ìlérí tí òun fúnrarẹ̀ ṣe fún wa ni ìyè ainipẹkun. Mò ń kọ nǹkan wọnyi si yín nípa àwọn kan tí wọn ń tàn yín jẹ; ẹ jẹ́ kí òróró tí Jesu ta si yín lórí máa gbé inú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí òróró rẹ̀ ninu yín ti ń kọ yín nípa ohun gbogbo, òtítọ́ ni, kì í ṣe irọ́, ẹ máa gbé inú rẹ̀, bí ó ti kọ yín. Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbé inú rẹ̀, kí á lè ní ìgboyà nígbà tí ó bá farahàn, kí ojú má baà tì wá láti wá siwaju rẹ̀ nígbà tí ó bá dé. Bí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ mọ̀ pé gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo ni ọmọ rẹ̀.

I. Joh 2:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀ wá, àní nísinsin yìí, púpọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fi mọ́ pé ìgbà ìkẹyìn ni èyí. Wọ́n ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́. Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́. Ta ni èké? Ẹni tí ó sẹ́ pé Jesu kì í ṣe Kristi. Eléyìí ni Aṣòdì sí Kristi: ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ. Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú. Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín. Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba. Èyí sì ni ìlérí náà tí ó tí ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun. Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín ní ti àwọn tí wọ́n fẹ́ ẹ mún un yín ṣìnà. Ṣùgbọ́n ní ti ìfóróróyàn tí ẹ̀yín gba lọ́wọ́ rẹ̀ ṣì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín. Ṣùgbọ́n bí ìfòróróyàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí ó jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀. Àti nísinsin yìí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ máa gbé inú rẹ̀, pé nígbà tí òun ó bá farahàn, kí a lè ni ìgboyà níwájú rẹ̀, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ ni ìgbà wíwá rẹ̀. Bí ẹ̀yin ba mọ̀ pé olódodo ni òun, ẹ mọ̀ pé a bí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe òdodo nípa rẹ̀.