I. Joh 2:15-17
I. Joh 2:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.
I. Joh 2:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ̀. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye. Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.
I. Joh 2:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ má fẹ́ràn ayé tabi àwọn nǹkan ayé. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ayé kò ní ìfẹ́ sí Baba. Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé. Ayé ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń kọjá lọ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóo wà títí lae.