I. Joh 2:12-14
I. Joh 2:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitori ẹnyin ti mọ̀ Baba. Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọ̀rọ Ọlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni buburu nì.
I. Joh 2:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu. Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba. Ẹ̀yin baba, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé inú yín, ẹ sì ti ṣẹgun Èṣù.
I. Joh 2:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ni agbára, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín, tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.