I. Joh 1:7-10
I. Joh 1:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo. Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa. Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.
I. Joh 1:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo. Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa. Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo. Bi awa ba wipe awa kò dẹṣẹ̀, awa mu u li eke, ọ̀rọ rẹ̀ kò si si ninu wa.
I. Joh 1:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa. Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa. Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa. Bí a bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀ rí, a mú Ọlọrun lékèé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí ninu wa.