I. Kor 9:24-25
I. Kor 9:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà. Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ.
I. Kor 9:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà. Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa.
I. Kor 9:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé.