I. Kor 9:22-23
I. Kor 9:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri. Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin.
I. Kor 9:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn. Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀.
I. Kor 9:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.