I. Kor 9:1-27

I. Kor 9:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

APOSTELI kọ́ emi iṣe bi? emi kò ha wà li omnira? emi ko ti ri Jesu Kristi Oluwa wa? iṣẹ mi kọ́ ẹnyin iṣe ninu Oluwa? Bi emi ki iṣe Aposteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Aposteli li emi iṣe fun nyin: nitori èdidi iṣẹ Aposteli mi li ẹnyin iṣe ninu Oluwa. Èsi mi fun awọn ti nwadi mi li eyi: Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu? Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa? Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ? Tani ilọ si ogun nigba kan rí ni inawo ara rẹ̀? tani igbìn ọgba ajara, ti ki isi jẹ ninu eso rẹ̀? tabi tani mbọ́ ọ̀wọ́-ẹran, ti kì isi jẹ ninu wàra ọ̀wọ́-ẹran na? Emi ha nsọ̀rọ nkan wọnyi bi enia? tabi ofin kò wi bakanna pẹlu bi? Nitoriti a ti kọ ọ ninu ofin Mose pe, Iwọ kò gbọdọ pa malu ti npaka li ẹnu mọ́. Iha ṣe malu li Ọlọrun nṣe itọju bi? Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀. Bi awa ba ti funrugbin ohun ti ẹmí fun nyin, ohun nla ha ni bi awa ó ba ká ohun ti nyin ti iṣe ti ara? Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi. Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ? Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere. Ṣugbọn emi kò lò ọ̀kan ninu nkan wọnyi: bẹ̃li emi kò si kọwe nkan wọnyi, nitori ki a le ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun mi: nitoripe o san fun mi ki emi kuku kú, jù ki ẹnikẹni ki o sọ ogo mi di asan. Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere. Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ. Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun. Nitori bi mo ti jẹ omnira kuro lọdọ gbogbo enia, mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo wọn, ki emi ki o le jère pipọ si i. Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin; Fun awọn alailofin bi alailofin (emi kì iṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi mbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jère awọn alailofin. Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri. Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin. Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà. Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ. Nitorina bẹ̃ni emi nsáre, kì iṣe bi ẹniti kò da loju; bẹ̃ni emi njà, ki iṣe bi ẹnikan ti nlu afẹfẹ: Ṣugbọn emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù.

I. Kor 9:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Ṣebí mo ní òmìnira? Ṣebí aposteli ni mí? Ṣebí mo ti rí Jesu Oluwa wa sójú? Ṣebí àyọrísí iṣẹ́ mi ninu Oluwa ni yín? Bí àwọn ẹlòmíràn kò bá tilẹ̀ gbà mí bí aposteli, ẹ̀yin gbọdọ̀ gbà mí ni, nítorí èdìdì iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ninu Kristi ni ẹ jẹ́. Ìdáhùn mi nìyí fún àwọn tí wọn ń rí wí sí mi. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ati láti mu ni? Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru? Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa? Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú? Kì í ṣe àpẹẹrẹ ti eniyan nìkan ni mo fi ń sọ nǹkan wọnyi. Ṣebí òfin náà sọ nípa nǹkan wọnyi. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu Òfin Mose pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di ẹnu mààlúù tí o fi ń ṣiṣẹ́ lóko ọkà.” Ǹjẹ́ nítorí mààlúù ni Ọlọrun ṣe sọ èyí? Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà. Nígbà tí a fúnrúgbìn nǹkan ẹ̀mí fun yín, ṣé ó pọ̀jù pé kí á kórè nǹkan ti ara lọ́dọ̀ yín? Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ? Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi. Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere. Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ. Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni. Kí wá ni èrè mi? Mo ní ìtẹ́lọ́rùn pé mò ń waasu ìyìn rere lọ́fẹ̀ẹ́, n kò lo anfaani tí ó tọ́ sí mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ni mo wà, tí n kò sì sí lábẹ́ ẹnìkan, sibẹ mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan kí n lè mú ọpọlọpọ wọn wá sọ́dọ̀ Jesu. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn Juu, èmi a máa di Juu kí n lè jèrè wọn. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí ó gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sábẹ́ Òfin Mose, kí n lè jèrè àwọn tí ó gba ètò ti Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gba ètò ti Òfin Mose fúnra mi. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sí ipò wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ka òfin Ọlọrun sí, pàápàá jùlọ òfin Kristi. Èmi a máa ṣe bẹ́ẹ̀ kí n lè jèrè àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn. Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀. Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà. Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa. Nítorí náà, aré tí èmi ń sá kì í ṣe ìsákúsàá láìní ète. Èmi kì í máa kan ẹ̀ṣẹ́ tèmi ní ìkànkukàn, bí ẹni tí ń kan afẹ́fẹ́ lásán lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà.

I. Kor 9:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa. Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa. Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni? Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran? Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì? Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi? Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè. Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara? Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù? Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìhìnrere Kristi. Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìhìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìhìnrere. Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù. Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú ààmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa