I. Kor 7:2-5
I. Kor 7:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nitori àgbere, ki olukuluku ki o ni aya tirẹ̀, ati ki olukuluku ki o si ni ọkọ tirẹ̀. Ki ọkọ ki o mã ṣe ohun ti o yẹ si aya: bẹ̃ gẹgẹ si li aya pẹlu si ọkọ. Aya kò li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe ọkọ: bẹ̃ gẹgẹ li ọkọ pẹlu kò si li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe aya. Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin.
I. Kor 7:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nítorí àgbèrè, kí olukuluku ọkunrin ní aya tirẹ̀; kí olukuluku obinrin sì ní ọkọ tirẹ̀. Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀. Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í. Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró.
I. Kor 7:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn.