I. Kor 7:1-40

I. Kor 7:1-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ niti awọn ohun ti ẹ ti kọwe: O dara fun ọkunrin ki o má fi ọwọ kàn obinrin. Ṣugbọn nitori àgbere, ki olukuluku ki o ni aya tirẹ̀, ati ki olukuluku ki o si ni ọkọ tirẹ̀. Ki ọkọ ki o mã ṣe ohun ti o yẹ si aya: bẹ̃ gẹgẹ si li aya pẹlu si ọkọ. Aya kò li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe ọkọ: bẹ̃ gẹgẹ li ọkọ pẹlu kò si li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe aya. Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin. Ṣugbọn mo sọ eyi bi imọran, kì iṣe bi aṣẹ. Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini. Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà. Ṣugbọn bi nwọn kò bá le maraduro, ki nwọn ki o gbeyawo: nitori o san lati gbeyawo jù ati ṣe ifẹkufẹ lọ. Ṣugbọn awọn ti o ti gbeyawo ni mo si paṣẹ fun, ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe Oluwa, Ki aya máṣe fi ọkọ rẹ̀ silẹ. Ṣugbọn bi o bá si fi i silẹ ki o wà li ailọkọ, tabi ki o ba ọkọ rẹ̀ làja: ki ọkọ ki o máṣe kọ̀ aya rẹ̀ silẹ. Ṣugbọn awọn iyokù ni mo wi fun, kì iṣe Oluwa: bi arakunrin kan ba li aya ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe kọ̀ ọ silẹ. Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ. Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́. Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia. Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là? Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ. A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla. Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́. Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e. A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini. Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi. A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia. Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun. Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo. Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃. A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni. Ṣugbọn bi iwọ ba si gbeyawo, iwọ kò dẹṣẹ: bi a ba si gbé wundia ni iyawo, on kò dẹṣẹ. Ṣugbọn irú awọn wọnni yio ni wahalà nipa ti ara: ṣugbọn mo dá nyin si. Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí; Ati awọn ti nsọkun, bi ẹ́nipe nwọn kò sọkun rí; ati awọn ti nyọ̀, bi ẹnipe nwọn kò yọ̀ rí; ati awọn ti nrà, bi ẹnipe nwọn kò ni rí; Ati awọn ti nlò ohun aiye yi bi ẹniti kò ṣaṣeju: nitori aṣa aiye yi nkọja lọ. Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa: Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀. Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀. Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn. Ṣugbọn bi ẹnikan ba rò pe on kò ṣe ohun ti o yẹ si wundia ọmọbinrin rẹ̀, bi o ba ti di obinrin, bi o ba si tọ bẹ̃, jẹ ki o ṣe bi o ti fẹ, on kò dẹṣẹ: jẹ ki nwọn gbé iyawo. Ṣugbọn ẹniti o duro ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, ti ko ni aigbọdọ máṣe, ṣugbọn ti o li agbara lori ifẹ ara rẹ̀, ti o si ti pinnu li ọkàn rẹ̀ pe, on o pa wundia ọmọbinrin on mọ́, yio ṣe rere. Bẹ̃ si li ẹniti o fi wundia ọmọbinrin funni ni igbeyawo, o ṣe rere: ṣugbọn ẹniti kò fi funni ni igbeyawo ṣe rere jù. A fi ofin dè obinrin niwọn igbati ọkọ rẹ̀ ba wà lãye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di omnira lati ba ẹnikẹni ti o wù u gbeyawo; kìki ninu Oluwa. Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.

I. Kor 7:1-40 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ẹ kọ nípa rẹ̀, ó dára tí ọkunrin bá lè ṣe é kí ó má ní obinrin rara. Ṣugbọn nítorí àgbèrè, kí olukuluku ọkunrin ní aya tirẹ̀; kí olukuluku obinrin sì ní ọkọ tirẹ̀. Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀. Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í. Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró. Mo sọ èyí kí ẹ lè mọ̀ pé mo yọ̀ǹda fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ni; kì í ṣe pé mo pa á láṣẹ. Ohun tí ìbá wù mí fun yín ni pé kí gbogbo eniyan rí bí mo ti rí; ṣugbọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun fún olukuluku yàtọ̀, ó fún àwọn kan ní oríṣìí kan, ó fún àwọn mìíràn ní oríṣìí mìíràn. Mò ń sọ fún àwọn tí kò ì tíì gbeyawo ati fún àwọn opó pé ó dára fún wọn láti dá wà, bí mo ti wà. Ṣugbọn bí wọn kò bá lè mú ara dúró, wọ́n níláti gbeyawo. Nítorí ó sàn kí wọ́n gbeyawo jù pé kí ara wọn máa gbóná nítorí èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin. Mo ní ọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ti gbeyawo: ọ̀rọ̀ tèmi fúnra mi kọ́, bíkòṣe ti Oluwa wa. Aya kò gbọdọ̀ kọ ọkọ rẹ̀. Bí ó bá kọ ọkọ rẹ̀, ó níláti dá wà ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ rẹ́, kí ó pada sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọkọ náà kò gbọdọ̀ kọ aya rẹ̀. Mo ní ọ̀rọ̀ fún ẹ̀yin yòókù, (èrò tèmi ni o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oluwa wa.) Bí ọkunrin onigbagbọ kan bá ní aya tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu aya rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ọkọ má ṣe kọ̀ ọ́. Bí obinrin onigbagbọ bá ní ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu ọkọ rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ó má ṣe kọ ọkọ rẹ̀. Nítorí ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa aya rẹ̀, aya tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa ọkọ rẹ̀. Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, alaimỌlọrun ni àwọn ọmọ yín ìbá jẹ́ ṣugbọn nisinsinyii ẹni Ọlọrun ni wọ́n. Ṣugbọn bí ẹni tí kì í ṣe onigbagbọ bá yàn láti fi ẹnìkejì tí ó jẹ́ onigbagbọ sílẹ̀, kí ó fi í sílẹ̀. Kò sí ọ̀ranyàn fún ọkọ tabi aya tí ó jẹ́ onigbagbọ ninu irú ọ̀ràn báyìí. Kí ẹ jọ wà ní alaafia ní ipò tí Ọlọrun pè yín sí. Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là? Kí olukuluku máa gbé ìgbé-ayé rẹ̀ bí Oluwa ti yàn án fún un, kí ó sì wà ní ipò tí ó wà nígbà tí Ọlọrun fi pè é láti di onigbagbọ. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń fi kọ́ gbogbo àwọn ìjọ. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ ẹni tí ó kọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe pa ilà rẹ̀ rẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìkọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe kọlà. Ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó ṣe pataki. Ohun tí ó ṣe pataki ni pípa àwọn òfin Ọlọrun mọ́. Kí olukuluku wà ní ipò tí ó wà nígbà tí a pè é láti di onigbagbọ. Ẹrú ni ọ́ nígbà tí a fi pè ọ́? Má ṣe gbé e lékàn. Ṣugbọn bí o bá ní anfaani láti di òmìnira, lo anfaani rẹ. Nítorí ẹrú tí a pè láti di onigbagbọ di òmìnira lọ́dọ̀ Oluwa. Bákan náà ni, ẹni òmìnira tí a pè láti di onigbagbọ di ẹrú Kristi. Iyebíye ni Ọlọrun rà yín. Ẹ má ṣe di ẹrú eniyan mọ́. Ẹ̀yin ará, ipòkípò tí olukuluku bá wà tí a bá fi pè é, níbẹ̀ ni kí ó máa wà níwájú Ọlọrun. N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé. Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí. Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo. Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ̀yin ará, ohun tí mò ń sọ nìyí. Àkókò tí ó kù fún wa kò gùn. Ninu èyí tí ó kù, kí àwọn tí wọ́n ní iyawo ṣe bí ẹni pé wọn kò ní. Kí àwọn tí ń sunkún máa ṣe bí ẹni pé wọn kò sunkún. Kí àwọn tí ń yọ̀ máa ṣe bí ẹni pé wọn kò yọ̀. Kí àwọn tí ń ra nǹkan máa ṣe bí ẹni pé kì í ṣe tiwọn ni ohun tí wọ́n ní. Kí àwọn tí ń lo dúkìá ayé máa lò ó láì dara dé e patapata. Nítorí bí ayé yìí ti ń rí yìí, ó ń kọjá lọ. Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbeyawo yóo máa páyà nípa nǹkan ti ayé yìí, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ iyawo rẹ̀ lọ́rùn; ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Fún ire ara yín ni mo fi ń sọ èyí fun yín, kì í ṣe láti dín òmìnira yín kù. Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí ẹ lè gbé irú ìgbé-ayé tí ó yẹ, kí ẹ lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ Oluwa, láìwo ọ̀tún tabi òsì. Ṣugbọn bí ọkunrin kan bá rò pé òun ń ṣe ohun tí kò tọ́ pẹlu wundia àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí wundia náà bá ti dàgbà tó, tí ọkunrin náà kò bá lè mú ara dúró, kí ó ṣe igbeyawo bí ó bá fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kí wọ́n ṣe igbeyawo. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pinnu ninu ọkàn rẹ̀, tí kò sí ìdí tí ó fi gbọdọ̀ ṣe igbeyawo, bí ó bá lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun yóo jẹ́ kí wundia òun wà bí ó ti wà, nǹkan dáradára ni ó ṣe. Ní gbolohun kan, ẹni tí ó bá gbé wundia rẹ̀ ní iyawo kò ṣe nǹkan burúkú. Ṣugbọn ẹni tí kò bá gbé e ní iyawo ni ó ṣe ohun tí ó dára jùlọ. A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́. Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun.

I. Kor 7:1-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn. Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ. Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀. Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà. Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà. Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi. Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá: èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo. Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà. Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí. Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ. Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ. A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa