I. Kor 7:1-11

I. Kor 7:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ẹ kọ nípa rẹ̀, ó dára tí ọkunrin bá lè ṣe é kí ó má ní obinrin rara. Ṣugbọn nítorí àgbèrè, kí olukuluku ọkunrin ní aya tirẹ̀; kí olukuluku obinrin sì ní ọkọ tirẹ̀. Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀. Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í. Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró. Mo sọ èyí kí ẹ lè mọ̀ pé mo yọ̀ǹda fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ni; kì í ṣe pé mo pa á láṣẹ. Ohun tí ìbá wù mí fun yín ni pé kí gbogbo eniyan rí bí mo ti rí; ṣugbọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun fún olukuluku yàtọ̀, ó fún àwọn kan ní oríṣìí kan, ó fún àwọn mìíràn ní oríṣìí mìíràn. Mò ń sọ fún àwọn tí kò ì tíì gbeyawo ati fún àwọn opó pé ó dára fún wọn láti dá wà, bí mo ti wà. Ṣugbọn bí wọn kò bá lè mú ara dúró, wọ́n níláti gbeyawo. Nítorí ó sàn kí wọ́n gbeyawo jù pé kí ara wọn máa gbóná nítorí èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin. Mo ní ọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ti gbeyawo: ọ̀rọ̀ tèmi fúnra mi kọ́, bíkòṣe ti Oluwa wa. Aya kò gbọdọ̀ kọ ọkọ rẹ̀. Bí ó bá kọ ọkọ rẹ̀, ó níláti dá wà ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ rẹ́, kí ó pada sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọkọ náà kò gbọdọ̀ kọ aya rẹ̀.

I. Kor 7:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn. Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ. Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.