I. Kor 6:1-20

I. Kor 6:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNIKẸNI ninu nyin, ti o ni ọ̀ran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pè e li ẹjọ niwaju awọn alaiṣõtọ, ki o má si jẹ niwaju awọn enia mimọ́? Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ? E kò mọ̀ pe awa ni yio ṣe idajọ awọn angẹli? melomelo li ohun ti iṣe ti aiye yi? Njẹ bi ẹnyin ni yio ba ṣe idajọ ohun ti iṣe ti aiye yi, ẹnyin ha nyan awọn ti a kò kà si rara ninu ijọ ṣe onidajọ? Mo sọ eyi fun itiju nyin. O ha le jẹ bẹ̃ pe kò si ọlọgbọn kan ninu nyin ti yio le ṣe idajọ larin awọn arakunrin rẹ̀? Ṣugbọn arakunrin npè arakunrin li ẹjọ, ati eyini niwaju awọn alaigbagbọ́. Njẹ nisisiyi, abuku ni fun nyin patapata pe ẹnyin mba ara nyin ṣe ẹjọ. Ẽṣe ti ẹnyin kò kuku gbà ìya? ẽṣe ti ẹnyin kò kuku jẹ ki a rẹ́ nyin jẹ? Ṣugbọn ẹnyin njẹni ni ìya, ẹ sì nrẹ́ ni jẹ, ati eyini awọn arakunrin nyin. Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́, Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun. Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa. Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun. Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara. Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀. Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri. Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan. Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan. Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀. Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin, Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.

I. Kor 6:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Kí ló dé tí ẹni tí ó bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkejì rẹ̀ fi ń gbé ẹjọ́ lọ siwaju àwọn alaigbagbọ? Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ? Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwa onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli! Mélòó-mélòó wá ni àwọn nǹkan ti ayé yìí? Bí ẹ bá ní ẹ̀sùn nípa nǹkan ti ayé, kí ló dé ti ẹ fi ń pe àwọn alaigbagbọ tí kò lẹ́nu ninu ìjọ láti máa jókòó lórí ọ̀rọ̀ yín? Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni? Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ! Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ? Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ! Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin; àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun. Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa. Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí. Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara. Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀. Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́! Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.” Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí. Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀. Àbí, ẹ kò mọ̀ pé ara yín ni ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà ninu yín, tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ati pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ni ara yín? Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun.

I. Kor 6:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa. “Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè; “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi. “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbèrè ṣíṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kristi fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kristi kí ń fi ṣe ẹ̀yà ara àgbèrè bí? Kí a má rí i! Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dàpọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè ń ṣe sí ara òun tìkára rẹ̀. Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.