I. Kor 3:5-9
I. Kor 3:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun. Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá. Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá. Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀. Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin.
I. Kor 3:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an. Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà. Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà. Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Nítorí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni wá lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ni ọgbà Ọlọrun. Tẹmpili Ọlọrun sì ni yín.
I. Kor 3:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.