I. Kor 3:21-23
I. Kor 3:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ki ẹnikẹni máṣe ṣogo ninu enia. Nitori tinyin li ohun gbogbo, Iba ṣe Paulu, tabi Apollo, tabi Kefa, tabi aiye, tabi ìye, tabi ikú, tabi ohun isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ̀; tinyin ni gbogbo wọn; Ẹnyin si ni ti Kristi; Kristi si ni ti Ọlọrun.
I. Kor 3:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo: ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo. Ṣugbọn ti Kristi ni yín, Kristi sì jẹ́ ti Ọlọrun.
I. Kor 3:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.