I. Kor 3:12-15
I. Kor 3:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi; Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe. Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère. Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja.
I. Kor 3:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá mọ wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta iyebíye, tabi igi, tabi koríko tabi fùlùfúlù lé orí ìpìlẹ̀ yìí, iṣẹ́ olukuluku yóo farahàn kedere ní ọjọ́ ìdájọ́, nítorí iná ni yóo fi í hàn. Iná ni a óo fi dán iṣẹ́ olukuluku wò. Bí ohun tí ẹnikẹ́ni bá kọ́ lé orí ìpìlẹ̀ yìí kò bá jóná, olúwarẹ̀ yóo gba èrè. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, olúwarẹ̀ yóo pòfo, ṣugbọn òun alára yóo lá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹni tí a fà yọ ninu iná ni.
I. Kor 3:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.