I. Kor 3:10-11
I. Kor 3:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.
I. Kor 3:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀lé tí ó mòye, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi, ẹlòmíràn wá ń kọ́lé lé e lórí. Ṣugbọn kí olukuluku ṣọ́ra pẹlu irú ohun tí ó ń mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. Nítorí kò sí ìpìlẹ̀ kan tí ẹnikẹ́ni tún lè fi lélẹ̀ mọ́, yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọrun ti fi lélẹ̀, tíí ṣe Jesu Kristi.
I. Kor 3:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà.