I. Kor 3:1-4
I. Kor 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ARÁ, emi kò si le ba nyin sọ̀rọ bi awọn ti iṣe ti Ẹmí, bikoṣe bi awọn ti iṣe ti ara, ani bi awọn ọmọ-ọwọ ninu Kristi. Wàra ni mo ti fi bọ́ nyin, kì iṣe onjẹ: nitori ẹ kò iti le gbà a, nisisiyi na ẹ kò iti le gbà a. Nitori ẹnyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ìja ati ìyapa ba wà larin nyin, ẹnyin kò ha jẹ ti ara ẹ kò ha si nrìn gẹgẹ bi enia? Nitori nigbati ẹnikan nwipe, Emi ni ti Paulu; ti ẹlomiran si nwipe, Emi ni ti Apollo; ẹnyin kò ha iṣe enia bi?
I. Kor 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, n kò lè ba yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ti Ẹ̀mí, bíkòṣe bí ẹlẹ́ran-ara, àní gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ ninu Kristi. Wàrà ni mo ti fi ń bọ yín, kì í ṣe oúnjẹ gidi, nítorí nígbà náà ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. Àní títí di ìsinsìnyìí ẹ kò ì tíì lè jẹ ẹ́, nítorí bí ẹlẹ́ran-ara ni ẹ̀ ń hùwà sibẹ. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí owú jíjẹ ati ìjà bá wà láàrin yín, ṣé kò wá fihàn pé bí ẹlẹ́ran-ara ati eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà. Nítorí nígbà tí ẹnìkan ń sọ pé ẹ̀yìn Paulu ni òun wà, tí ẹlòmíràn ń sọ pé ẹ̀yìn Apolo ni òun wà ní tòun, ó fihàn pé bí eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.
I. Kor 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi. Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a. Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí? Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”