I. Kor 2:7-10
I. Kor 2:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun.
I. Kor 2:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́, Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí, ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.” Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun.
I. Kor 2:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ojú kò tí ì rí, etí kò tí í gbọ́, kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀ ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ.