I. Kor 2:6-16

I. Kor 2:6-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan: Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun. Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun. Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá. Ohun na ti awa si nsọ, kì iṣe ninu ọ̀rọ ti ọgbọ́n enia nkọ́ni, ṣugbọn eyiti Ẹmí Mimọ́ fi nkọ́ni; eyiti a nfi ohun Ẹmí we ohun Ẹmí. Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn. Ṣugbọn ẹniti o wà nipa ti ẹmí nwadi ohun gbogbo, ṣugbọn kò si ẹnikẹni ti iwadi rẹ̀. Nitoripe tali o mọ̀ inu Oluwa, ti yio fi mã kọ́ ọ? Ṣugbọn awa ni inu Kristi.

I. Kor 2:6-16 Yoruba Bible (YCE)

À ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún àwọn tí igbagbọ wọn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, kì í sìí ṣe ti àwọn aláṣẹ ayé yìí, agbára tiwọn ti fẹ́rẹ̀ pin. Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́, Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí, ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.” Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun. Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa. Ohun tí à ń sọ kì í ṣe ohun tí eniyan fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kọ́ wa. Ẹ̀mí ni ó kọ́ wa bí a ti ń túmọ̀ nǹkan ti ẹ̀mí, fún àwọn tí wọ́n ní Ẹ̀mí. Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé. Ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí lè wádìí ohun gbogbo, ṣugbọn eniyan kan lásán kò lè wádìí òun alára. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ta ni ó mọ inú Oluwa? Ta ni yóo kọ́ Oluwa lẹ́kọ̀ọ́?” Ṣugbọn irú ẹ̀mí tí Kristi ní ni àwa náà ní.

I. Kor 2:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ojú kò tí ì rí, etí kò tí í gbọ́, kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀ ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnrarẹ̀. Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀. “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa, ti yóò fi máa kọ́ Ọ?” Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.